Tramadol: Ọwọ́ tẹ afurasí méjì tó kó òògùn olóró N60m wọlé l'Apapa

Awọn oṣiṣẹ aṣọbode

Ọwọ awọn oṣiṣẹ aṣobode lebute ọkọ oju-omi to wa l'Apapa nipinlẹ Eko, ti tẹ awọn afurasi meji kan ti wọn ko oogun Tramadol wọ Naijiria lọna aitọ.

Alakoso awọn oṣiṣẹ aṣọbode l'Apapa, Muhammed Abba Kura ṣalaye pe, awọn oogun Tramadol ọhun to ọgọta miliọnu Naira.

O fikun ọrọ rẹ pe, ninu ọkọ itọju alaisan pajawiri taa mọ si ambulance lawọn afurasi meji ọhun kọkọ ko oogun naa si.

Lẹyin ti ọwọ tẹ wọn tan, ni awọn oṣiṣẹ aṣọbode tun rii wi pe oogun Tramadol tun kun inu agolo ikẹru si, ti wọn n pe ni ''container'' bamu.

Awakọ ati oṣiṣẹ ile iṣẹ kan lawọn afurasi meji ọhun tọwọ sinkun ofin ti ba bayii.

Awọn oṣiṣẹ aṣọde ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.