Kí ló máa ń wú ìyá Nike Davies lori láti wé gèlè ràbàtá?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nike Davies-Okundaye: Àṣírí tó wà nídìí ìmúra mi

"... bí a ò bá dé adé, adé tèmi lẹ rí yẹn o!".

Arabinrin Nike Davies-Okundaye kii ṣe ọmọde rara ninu iṣẹ to yan laayo ati gẹgẹ bi agbaṣa ga ọmọ orilẹede Naijiria.

Ọmọ ilu Ogidi Ijumu ni ipinlẹ Kogi nii ṣe.

Oniruuru oye ni wọn ti fi da a lọla latari ko maa gbe aṣa ibilẹ ga, lara rẹ ni Yeye Agbaṣaga.

Iṣẹ ọna ati yiya aworan to yan laayo ko ba a mọ lorilẹede Naijiria nikan, ṣe lo ti gbe e pade awọn ọlọla to si ti mu u rinrinajo kaakiri agbaye.

Iṣẹ ti iya-iya-iya rẹ kọ ọ ni ti wọn si fi le e lọwọ ni ti oun naa ko si jẹ ko parun.

Awọn Iroyin ti ẹ le nifẹ si

Gẹgẹ bi Mama Nike Davies ṣe ṣi ni loju lori iru iṣẹ yii, o ni "o lere lori ṣugbọn wahala rẹ pọ".