Afonja: Ọ̀rẹ́ àjèjì ló kó bá Afọnja, tí Ilọrin fi bọ́ lọ́wọ́ Yorùbá

Aarẹ Ọna Kakanfo Afọnja tilu Ilọrin
Àkọlé àwòrán,

Afọnja gba ilu Ilọrin labẹ akoso ilu Ọyọ, to si kede pe ilu naa ti di ilu olominira

Laarin ọdun 1700, paapa ọdun 1750, ọkunrin akọni kan lalẹ hu ni ilu Ọyọ ti orukọ rẹ n jẹ Afọnja, to si kẹrẹkẹrẹ di Aarẹ Ọna Kakanfo fun ilẹ Yoruba eyi to safihan bo ti jẹ akikanju to.

Lara awọn orukọ ọmọ ilẹ Kaarọ Oojiire ti a ko si lee gbagbe ni Afọnja wa, ta ba si se n ranti Afọnja, naa la ma ranti ilu Ilọrin, nibi ti Afọnja tẹdo si dọjọ alẹ.

O tun seese ki iran Yoruba ma lee gbagbe Afọnja nitori ipa to ko nilu Ilọrin ati awọn isẹlẹ to sẹlẹ nibẹ, eyi to si n ja rainrain nilẹ titi di asiko ta wa yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi itan atẹnudẹnu ti jẹ ko ye wa, to fi mọ oju opo Wikipedia ati Facebook , a ko lee pe ori aja, ka ma peri ikoko ta fi se e, ni ọrọ Afọnja, ilu Ilọrin ati Ọyọ ile jẹ, nitori pe wọn tan mọ ara wọn.

N jẹ bawo ni itan igbe aye Afọnja se lọ, ipa wo lo ko si idagbasoke iran Yoruba, ki si ni awọn isẹ to gbe ile aye se ta fi n ranti rẹ di oni yii ati isẹlẹ to waye laarin rẹ ati ẹya Fulani.

Itan igbesi aye Afọnja:

 • Laderin, tii se ọmọ bibi ọkunrin kan ti wọn n pe ni Alugbin, toun naa jẹ ọmọ bibi inu Pasin, lo bi Afọnja. Ilu kan ti wọn n pe ni Jabata si ni Afọnja ti wa
 • Lasiko ti Alaafin Abiọdun wa lori itẹ awọn baba nla rẹ, ni Afọnja jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo, titi ti Alaafin Aolẹ, tii se ọmọ bibi Alaafin Abiọdun fi gori itẹ lẹyin to seku pa baba rẹ
 • Ni kete to jẹ oye akọni yii tan, ni Afọnja lọ tẹdo silu Ilọrin nitori pe Aarẹ Ọna Kakanfo kankan kii gbe ni ilu kannaa pẹlu Alaafin, ọga meji kii sa gbe ninu ọkọ kan, agbo meji ko si lee mu omi ninu koto kan soso
 • Afọnja ni Aarẹ Ọna Kakanfo kẹfa, amọ ko pẹ rara ti ija de, ti orin si di owe laarin rẹ ati Alaafin Aolẹ, eyi ta lee ni o se okunfa bi awọn ẹya Fulani se gba Ilọrin mọ ilẹ Yoruba lọwọ.
Àkọlé àwòrán,

Ni kete ti Afọnja pada de lati Apomu lo gba aafin Ọyọ lọ, to si ni ki Alaafin Aolẹ funra ara rẹ fi ori apere silẹ

Ki lo sokunfa aawọ nla laarin Afọnja ati Alaafin Aolẹ?

 • Ilẹ ti Afọnja mu pẹlu Alaafin Abiọdun, ti ko si fẹ dalẹ, lo sokunfa aawọ to waye laarin rẹ ati Alaafin Aolẹ nitori pe Afọnja kọ jalẹ lati lọ fi ogun ja ilu Iwere Ile, tii se ilu iya Alaafin Abiọdun, ko si sẹni to ye lori idi ti Alaafin Aolẹ fi fẹ ko ogun ja ilu iya baba rẹ
 • Imulẹ ati Epe si ti wa nilẹ tẹlẹ ti Alaafin Abiọdun ṣẹ pe Aarẹ Ọna Kakanfo to ba ko ogun ja ilu Iwere Ile yoo ku iku radarada , rederede ni, idi si ree ti Afọnja se fi aake kọri lati mu asẹ Alaafin Aolẹ ṣẹ
 • Amọ Aolẹ fi ẹjẹ dudu sinu, to si n tu itọ funfun jade lori isẹlẹ naa, lo ba ran Afọnja ni isẹ miran lọdun 1795, pe ko lọ ko ogun ja ilu Apomu, to wa labẹ ilu Ile Ifẹ lasiko naa, tii se orirun iran Yoruba
 • Afọnja se isẹ ti Aolẹ ran lootọ, amọ ni kete to pada de lo gba aafin Ọyọ lọ, to si ni ki Alaafin Aolẹ funra ara rẹ fi ori apere silẹ, eyi si lo mu ki Aolẹ gbe nkan jẹ, to si gbẹmi ara rẹ
 • Lootọ lawọn Alaafin kan jẹ lẹyin Aolẹ, amọ ko pẹ ti gbogbo wọn fi waja, titi di ọdun 1802 ti Alaafin Majotu jọba, lati akoko yii si ni Afọnja ti n tiraka lati fi agbara kun agbara rẹ eyi to papa bu lọwọ
 • Afọnja gba ilu Ilọrin labẹ akoso ilu Ọyọ, to si kede pe ilu naa ti di ilu olominira.
Àkọlé àwòrán,

Abdulsalam lo ede rẹ lati fi gba awọn ọmọ ogun Afọnja, ti wọn si gba ẹmi Afọnja lọdun 1817

Ibẹrẹ iṣubu Afọnja lati ọwọ Fulani nilu Ilọrin:

 • Afọnja gbagbọ pe awọn ọmọ ogun Fulani ati awọn ẹru to jẹ Hausa jẹ akikanju jagunjagun, ti wọn si sangun ju awọn ọmọ ogun toun lọ, idi niyi to se ba Shehu Alimi, tii se Aafa Fulani da ọrẹ, Afọnja si tu awọn ọmọ ogun tiẹ ka, to si ko awọn ẹya Hausa, Fulani atawọn ẹya miran sinu ikọ ọmọ ogun rẹ
 • Lẹyin ti Alimi ku, Abdulsalam tii se ọmọ Alimi lo anfaani ohun ti Afọnja se yii, to si loo lati kọlu Afọnja. Abdulsalam lo ede rẹ lati fi gba awọn ọmọ ogun Afọnja, ti wọn si gba ẹmi Afọnja lọdun 1817
 • Nigba to di ọdun 1824 lẹyin ti Afọnja papoda, ti Abdulsalam si ti n dari ilu Ilọrin, lo ba kede ara rẹ bii Emir fun ilu Ilọrin, to si sọ pe lati akoko naa lọ, ilu Ilọrin ti wa labẹ akoso Emir ilu Sokoto
 • Lati igba naa wa ni akoso ilu Ilọrin ti bọ mọ ẹya Yoruba lọwọ titi di oni oloni, bi o tilẹ jẹ pe awọn iran Yoruba n tiraka lati gba ipo wọn pada lọwọ ẹya Fulani nilu Ilọrin, amọ wọn kan n le ni, wọn ko tii ba

Ọpọ ẹkọ lo wa lara itan Afọnja yii, eyi to yẹ ka mu lo lode oni nitori ẹni to jin si koto, yẹ ko kọ awọn ara yoku lọgbọn, itakun kansoso ko si yẹ ko da wa lepo nu lẹẹkeji.

Ọgbọn ti itan Afọnja kọ wa:

 • Itan Afọnja kọ wa lati maa mu ẹjẹ wa si ẹnikeji sẹ boya onitọun wa laye abi o ti jade laye
 • O tun kọ wa lati jẹ olootọ si ẹni to ba se wa loore
 • Itan naa tun kọ wa lati mase ta ara ile abi ẹya wa lọpọ, nitori o seese ka ma ri ra ni ọwọn gogo mọ
 • A tun ri kọ pe tẹni n tẹni, ekisa n taatan, ara ile ẹni ko seni, eniyan ẹni ko seniyan, ko ni jọ alaroo lasan, ẹbi ẹni ni ẹbi ẹni
 • Itan naa tun jẹ ka mọ pe ka maa fura, ka si maa kiyesara nipa awọn alejo to ba wọle tọ wa, ka si mase tete dara de wọn, nitori ewu lee wa loko Longẹ, Longẹ gan ewu ni.
 • O yẹ ka kọgbọn pe, lọpọ igba ko yẹ ka maa fi inu wenu, paapa pẹlu awọn ajeji, ka maa baa jẹ iwọ.