Ọọ̀ni: Ìpèníjà ààbò di ìràwọ̀ ọ̀sán tó ń ba àwa àgbà lẹ́rù

Oba Adeyeye Ogunwusi ati aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright Oba Adeyeye Ogunwusi

Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji, ti keboosi too fun aarẹ Muhammadu Buhari lori ipenija eto aabo to n ba ilẹ Yoruba finra.

Ọba Ogunwusi, ẹni to ke gbajare yii tọ aarẹ Buhari lọ lọjọbọ nilu Abuja tun kede pe, awọn ajeji ti gba akoso nilẹ Yoruba, ti ipenija eto aabo to n koju wa si jẹ ara eyi to n koju orilẹede Naijiria lapapọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọrọ lorukọ awọn oriade to ku nilẹ Yoruba, Ọọni tun tẹnumọ pe, ominu n kọ awọn ọba alaye to wa nilẹ Kaarọ Oojire lọwọlọwọ bayii, nitori ipenija eto aabo naa ti di irawọ ọsan, to n ba awọn agba lẹru.

Arole Oodua wa jẹjẹ pe oun atawọn ọba alaye yoku ti setan lati fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba, ti wọn si n beere fun afikun eto aabo latọdọ ijsba apapọ, ki wọn lee daabo bo awọn eeyan wọn lọwọ awọn kanda inu irẹsi, o si seese ki wọn ma jẹ ẹya Fulani.

Image copyright Oba Adeyeye Ogunwusi

Amọ sa, Ọọni wa fọrọ ransẹ si awọn eeyan to n lu ilu ogun jija, to fi mọ awọn oloselu ti wọn di esu to n ta epo si ọrọ naa pe, ki wọn ti ọwọ ọmọ wọn bọ asọ lori awọn iwa naa.

O ni iru iwa yii lo lee mu idarudapọ waye lorilẹede Naijiria, toripe orilẹede yii ko tun le fi oju wina ogun.