Russia infanticide: 11,000 ọmọdé làwọn òbí ti pa láàrin ọdún 1976 sí 1997

apejuwe

Ọpọ ninu awọn obinrin lo maa n jẹjọ lori ẹsun pe, wọn ṣeku pa ọmọ ti wọn bi fun ra wọn.

Ọpọ ninu wọn lo jẹ iyawo ile, ti awọn miiran si jẹ gbajugbaja oniṣowo.

Amọ, kii ṣe orilẹede Russia nikan ni iru iṣẹlẹ bayii ti n ṣẹlẹ. Iwadii fihan pe, ọkan ninu awọn obinrin mẹrin l'Amẹrika lo ti gbero lati gbẹmi ọmọ wọn.

Iwadi kan lorilẹede Amẹrika fihan pe, laarin ọdun 1976 si 1997, eyiun ọdun laarin ọdun mọkanlelogun, awọn ọmọde tawọn obi wọn ti pa to ẹgbẹrun mọkanla.

Eyi tumọ si pe awọn ọmọde toto okoolelọọdunrun (340), lawọn obi wọn n sekupa pa laarin ọdun kan soso.

Ṣugbọn lorilẹede Russia, gẹgẹ bi o ti rii lọpọlọpọ orilẹede naa, o nira lati gbaye gbadun nitori ọrọ aje to dẹnu kọ lẹ.

Awọn Eewọ:

Awọn akọroyin BBC lorilẹede Russia, Olesya Gerasimenko ati Svetlana Reiter beere lọwọ awọn obinrin ni Russia, idi abajọ ti wọn n fi pa ọmọ ti wọn bi.

Iṣẹ iwadii wọn yii tun se afihan idi to fi ṣe pataki lati gbe iru aṣa bẹẹ ṣẹgbẹ kan.

Alyona:

Alyona jẹ onimọ nipa eto ọrọ-aje, o fẹ ọkọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Pyotr, wọn si jọ n reti ọmọ.

Wọn ra aṣọ, wọn si se gbogbo eto to yẹ ni ireti ọmọ tuntun to n bọ, ṣugbọn ko sẹni to ranti nipa aisan ailera to le ṣẹyọ lẹyin ibimọ.

Lẹyin to bimọ tan, Alyona ni aarun otutu aya, eyi to ko si ninu ọpọlọ, ti iwa rẹ ko si fii bẹẹ jọ ti eeyan ti ọpọlọ rẹ pe.

Ọkọ rẹ, Pyotr ba oku ọmọ oṣu meje ni baluwẹ lọjọ kan to pada sile, o si ri Alyona iyawo rẹ lẹgbẹ odo kan ni abawọlu Moscow, nibi to ti n mu ọti Vodka.

Ni bayii, Alyona n jẹjọ lọwọ lori ẹsun naa, ti ọkọ rẹ maa n gbiyanju lati tu u ninu nigba kuugba ti wọn ba lọ si ileẹjọ.

Pyotr gbagbọ pe, iṣẹlẹ naa ko ba ti ṣẹlẹ ti awọn ba mọ nipa aisan to n se abiyamọ lẹyin ibimọ.

Irufẹ isẹlẹ ki obi gbẹmi ọmọ rẹ bayii si to mẹtalelọgbọn ti wọn gbọ ẹjọ rẹ lọdun 2018 nikan ni orilẹede Russia, awọn eeyan to n sewadi iwa ọdaran si fi idi rẹ mulẹ pe ilọpo mẹjọ irufẹ ẹsun yii lo n waye lai jẹ pe o dele ẹjọ.