Oluwo: Inú ìwé kíkà ni ọja ọ̀la àwọn Fulani wà

Oluwo ti Iwo Image copyright Instagram/Oluwo of Iwoland

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, Telu Kinni, ti kesi ijọba apapọ lorilẹede Naijiria lati sọ ileewe lilọ di dandan fun awọn ọmọ ẹya Fulani.

Oluwo fi ọrọ yii sita loju opo ayelujara Instagram rẹ, lẹyin ti oun ati awọn ọba alaye to le ni ogun, ṣe abẹwo ikinni ku oriire si Gomina Gboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun, lọọfisi rẹ.

O ni ailọ sileewe awọn ọmọ naa, to jẹ iṣẹ maalu dida kiri nikan ni wọn fi nkọ wọn, jẹ ara nkan to n fa iwa jagidijagan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oluwo ni o ṣe pataki ki ijọba ṣe ofin pe, ki awọn ọmọ Fulani maa lọ si ileewe, bi ko tilẹ kọja ileewe girama, lati le ṣe eto ọjọ iwaju to dara fun ẹya naa.

''Mo maa n bẹ awọn Fulani to wa ninu ilu mi wo. Bi mo ṣe maa n bẹ wọn lati ran awọn ọmọ wọn lọ sileewe, naa ni mo maa n kilọ pe, maa fi ofin gbe awọn obi wọn to ba kọ lati fun awọn ọmọ wọn ni ẹkọ to dara.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwo: Mo lè jẹ Ọba ní Ile Ife

Ọba alaye naa fikun pe aisi ẹkọ iwe lo maa n se okunfa iwa jagidi-jagan. Ijiya ẹ́sẹ́ fawọ̀n ajinigbe ko si lọ̀ titi, amọ eto ẹkọ to ye kooro si lo le wa ojutu laelae si isoro naa.