Olakunrin murder: Ọlọ́pàá ní OPC kò láṣẹ láti fipa lé ẹ̀yà kan nílẹ̀ Yorùbá

Funke Olakunrin Image copyright Funke Olakunrin

Ile iṣẹ ọlọpaa ti sọ pe, ẹgbẹ apapọ ọmọbibi Oodua, Oodua Peoples Congress (OPC), igun ti New Era, ko laṣẹ labẹ ofin lati fipa le eya kan kuro nilẹ Yoruba.

Eyi ni esi agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Ondo, Femi Joseph si atẹjade kan ti OPC, New Era fi sita lọjọbọ.

OPC New Era ni awọn ọmọ ẹgbẹ awọn yoo bẹrẹ si ni le awọn Fulani darandaran to n hu iwa ọdaran ni gbogbo awọn ipinlẹ to jẹ ti ẹya Yoruba jade, tawọn ile iṣẹ eto aabo ko ba foju awọn to ṣeku pa arabinrin Funke Olakunrin han.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa ni, ofin Naijiria faye gba ẹyakẹya lati lọ si ipinlẹ miiran, bakan naa lofin faye gba wọn lati ni dukia nibi kibi ti wọn ba wa lorilẹede Naijiria.

Ọgbẹni Joseph sọ pe, ijọba nikan lo laṣẹ lati sọ pe ki ẹnikẹni kuro ni ipinlẹ kan tabi nibikibi lorilẹede Naijiria.

O wa rọ ẹgbẹ OPC, New Era lati fọwọsowọpọ pẹlu ile iṣẹ ọlọpaa lori iṣẹ iwadii ti wọn n ṣe, lori iku arabinrin Olakunrin.

Image copyright other

Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa tun rọ ẹgbẹ OPC pe ki wọn ni suuru kọrọ naa maa ba di ija.

Ọgbẹni Joseph ni iṣẹ iwadii ṣi n lọ lori ọrọ naa, pẹlu afikun pe ko yẹ ki ẹgbẹ OPC maa dunkoko mọ awọn ọlọpaa nitori iṣẹ iwadii lori iṣekupani maa n gba suuru ati akoko.

Ọlọ́pàá, a fún yín ní gbèdéke ọjọ́ 21 láti mú àwọn tó pa ọmọ Fasoranti - OPC

Ẹgbẹ Oodua Peoples Congress (OPC), New Era, ti fun ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ileeṣẹ eto aabo mi i l'orilẹede Naijiria ni gbedeke ọjọ mọkanlelogun lati tu aṣiri awọn to pa Abilekọ Funke Olakunrin, ọmọ olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Alagba Reuben Fasoranti.

Ẹgbẹ naa ninu atẹjade kan to fi sita l'Ọjọru nilu Ibadan lati ọwọ Alukoro Apapọ rẹ, Comrade Adeshina Akinpẹlu, sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ awọn yoo bẹrẹ si ni le awọn Fulani darandaran to n hu iwa ọdaran ni gbogbo awọn ipinlẹ to jẹ ti ẹya Yoruba jade, to fi mọ awọn agbodegba wọn laarin awọn ọmọ Yoruba ati ẹya miran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí

Ọjọ Ẹti to kọja ni awọn kan pa Abilekọ Ọlakunrin loju ọna Ore si Sagamu.

''Asiko ti to fun wa lati gbe igbesẹ, a ko kan nii kawọ gbera maa wo ki wọn maa fi ẹjẹ awọn eniyan wa daabo bo iṣọkan Naijiria.

"Kikuna lati mu awọn apaniyan naa sita, ko ni ṣi nkan mii fun wa lati ṣe ju pe ka daabo bo awọn eniyan wa lọ, ka si le gbogbo awọn ọdaran Fulani darandaran kuro laarin wa."

Lori bi ẹgbẹ awọn darandaran ni Naijiria, Miyetti Allah, ṣe ni ki wọn fi ofin gbe aarẹ Naijiria nigba kan, Olusegun Obasanjo nitori lẹta to kọ si arẹ Muhammad Buhari lori ọrọ eto aabo ni Naijiria laipẹ yii, ẹgbẹ OPC sọ pe ki ẹgbẹ Miyetti Allah ''ṣọra lati maa wa ẹni ti wọn fẹ fi j'ofin fun awọn iwa ti ko tọ ti wọn n hu.''