Dandan ni bàyíì fún àwọn màálù ni Uganda láti gba ìwé ọjọ́ ìbí

Maalu Image copyright Getty Images

Gbogbo maalu l'orilẹede Uganda yoo bẹrẹ si ni gba iwe ọjọ ibi laipẹ, ko le baa rọrun lati tọ pinpin ibi ti wọn ti wa.

Eyi ri bẹẹ ki wọn o le maa tẹle ilana lati ọdọ ajọ ilẹ Yuroopu.

Gẹgẹ bi Minisita fun eto iṣẹ ọgbin, itọju ẹranko ati ọsin ẹja, Vincent Ssempijja, ṣe sọ, awọn orilẹede to n pese ounjẹ fun ẹja nilẹ Yuroopu gbọdọ fi ẹri ibi ti ounjẹ naa ti wa han.

O sọ pe ilana yii ṣe pataki pupọ fun awọn agbẹ nitori pe wọn yoo fẹ mọ ibi ti maalu ti wa, ati ọjọ ori maalu naa, nitori pe wọn fẹran ẹran maalu ti ọjọ ori rẹ ko ju oṣu mẹẹdogun si ọdun meji lọ.

Bakan naa ni Minisita naa sọ pe ajọ EU ti fi igba kan gbẹsẹ le, ti wọn si tun fi ofin de awọn ọja to wa lati Uganda. O ni "nitori eyi lo ṣe ṣe pataki ki awọn agbẹ o gba lati fi orukọ silẹ."

Ilana eto naa ni pe "awọn agbẹ yoo fi oruk ara wọn silẹ, gbogbo ere oko tabi ẹran ọsin to wa lati ọdọ wọn yoo maa ni ami idanimọ pataki.

Eyi yoo mu ki o rọrun lati mọ orisun ibi ti ọja kankan to ba ni wahala ninu ti wa."

Iṣẹ agbẹ jẹ ọkan gboogi ninu eto ọrọ aje Uganda, nitori pe o n gba to ìdá aadọrin awọn eniyan orilẹede naa si iṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Awọn Iroyin ti ẹ le nifẹ si