Africa in Pictures: Àwọn àwòràn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti ilẹ̀ Afirika

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọbinrin akẹkọ mẹta ni orilẹede Sierria Leone to n ti ile iwe bọ, sa si abẹ́ aburada kansoso lasiko ti ojo n rọ. Eyi tumọ̀ si pe bi ifẹ ba wa, yara kekere gba ọpọ eeyan, inu ko gba, ni aaye ko gba
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdọọdun ni awọn adan maa n rababa yika oju ọdun nilu London, lati fo pada wa si ilẹ Afrika. Aworan yii lo si n fi ye wa pe oju ọrun to ẹyẹ fo lai fi apa kan ara wọn
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Iya ati ọmọ lo tu jade ni Khartoum, lorilẹede Sudan lati se iwọde tako ijọba ologun. Eyi tumọ si pe kaka ki ẹlulu ma dun ọbẹ, tapa titan rẹ ni yoo run si
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Inu ẹni kii dun, ka pa mọra. Sugbọn ere itage alafi orin kọ ni obinrin yii n se ni orilẹede Tunisia
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ero ree lode lasiko ti akọrin adulawọ kan, Aya Nakamura bọ sori itage lati kọrin lasiko ajọdun orin lorilẹede South France. Ero yii ti pọju
Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Haa, awọn obinrin lo n luwẹ bii ẹja yii, ohun ti ọkunrin lee se, awọn obinrin naa le se e. orilẹede South Korea ni idije iwẹ lilu lagbaye naa ti n lọ lọwọ
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Agbara ju agbara lọ, ọgbọn ju ọgbọn lọ. Eeyan kan ree to n dẹgbẹ lori okun lai si lori ọkọ oju omi, Huu, nkan n bẹ
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọlọrun ma jẹ ki itan yii fa ya, ki lo le to eyi. Anice Badri ọmọ orilẹede Tunisia ree to ya itan de agbari
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ara meeriri ree o. Okuta posi kan ree ti wọ̀n ya aworan si lara eyi ti wọn se awari rẹ nilu Cairo lorilẹede Egypt lọjọ Satide