Ayinla Kollington: Ìyàwó mí títí láéláé ni Salawa Abẹni

Alhaji Kollington Ayinla

Gbajugbaja olorin Fuji nni, Alhaji Ayinla Kollington ti kede fun araye pe titi aye ni akọrin Waka nni, Alhaja Salawa Abẹni yoo maa jẹ iyawo oun, ti awọn yoo si jọ pẹ fun ara awọn.

Kollington, ẹni to kede eyi lasiko to n dahun ibeere lori eto BBC Yoruba, tun salaye pe obinrin to bi ọmọ fun ni, ti kuro ni ale ẹni, ọmọ mẹta si ni Salawa Abẹni bi fun oun, nitori naa, iyawo oun nii se.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O tun fikun pe, laipẹ ni oun ati Salawa Abẹni yoo dijọ se awo orin jade, koda, ọmọ awọn to n kọ orin takasufe, Big Chef, ti oun gan yoo se awo orin naa papọ pẹlu awọn mejeeji.

Bakan naa ni Kollington kede pe baba Kebe ni oun, baba 'Yuppie', nitori pe to ba di ere lọkọlaya, ara oun si n ta kebe, eegun oun si tun n le.

Nigba to n salaye nipa ẹni to da orin Fuji silẹ nilẹ Yoruba, Kollington kede pe, oun ati Alhaji Sikiru Ayinde Barrister ni awọn dijọ bẹrẹ orin Fuji ni akoko kan naa tawọn dijọ wa ninu isẹ ologun, bi o tilẹ jẹ pe orin Fuji ti wa tipẹ ki awọn to bẹrẹ si ni gbe larugẹ.

Kollington, ẹni to gbosuba fun Barrister to wa wọ kuro lẹnu isẹ sọja, wa kan saara si oloogbe naa pe, ti kii ba se ti Barrister ni, isẹ asọna ni oun ko ba maa se.

O fikun pe ọpọ ija ti oun ati Barrister maa n ja kii se pe awọn n se ọta, amọ ija orogun owo lasan ni, ti awọn si maa n lọ sile ara awọn lati jẹun eyi ti ko han si ọpọ ololufẹ awọn to n tori awọn mejeeji ja lainidi.

Kollington tun salaye pe awọn ololufẹ awọn lo maa n da ija silẹ laarin oun ati Barrister nitori iwa gbọyi-sọyi ti wọn maa n se, ti wọn si maa n ti awọn lati fi orin owe bu ara awọn.

Kollington tun yannana rẹ pe oun n selede lẹyin Barrister, ti oun ko si jẹ ki ile rẹ daru, koda, awọn ọmọ rẹ gan ti ri oun bii baba wọn, ti wọn si maa n wa fi ọrọ ati ise wọn lọ oun lati tọ wọn sọna.

Baba Alatika wa kede pe oun n fẹ ọjọ ọla rere fun orin Fuji, ti oun ko si fẹ ki olorin Fuji kankan ja mọ nitori orogun owo, bakan naa lo si gba awọn olorin iwoyi nimọran lati mase maa fi ede ajeji kọ orin Fuji nitori tiwa n tiwa, akisa ni ti aatan.

Kollington lasiko to n gba ijọba ilẹ wa ni imọran, gba awọn olori wa nimọran, lati maa ranti mẹkunnu, nipa ipese awọn ohun eelo amayedẹrun, papa atunse oju popo.

Kebe n Kwara, ẹni to ni ko yẹ ki orilẹede Naijiria tii gba ominira, wa gba awọn araalu nimọran lati sugba ijọba Buhari nitori pe ilu ko rọ̀run nigba ti Buhari gba ijọba pẹlu afikun pe iwa ajẹ́banu ko lee tan lara awọn ọmọ Naijiria.