Ruga: Ọ̀pọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tó ń fẹ́ Ruga ló wá láti apá òkè ọya

Awọn maalu to n jẹko Image copyright Getty Images

Agbekalẹ abule Fulani ti wọn n pe ni Ruga lo ti n fa awuyewuye ni orilẹede Naijiria lẹnu lọọlọ yii, ti awọn ipinlẹ kan si tako igbesẹ naa eyi to mu ki ijọba Muhammadu Buhari sẹwele igbesẹ ọhun.

Ọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ, awọn lookọ lookọ lawujọ, awọn oriade, asaaaju ẹsin to fi mọ awọn gomina ipinlẹ kọọkan lo ti sọ ero ọkan wọn lati tako tabi faramọ agbekalẹ abule Ruga naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn iwadi BBC ti fihan pe, ọrọ naa ti di ẹkọ ẹlẹkọ ni ẹgba ẹlẹgba bayii nitori awọn ipinlẹ kan ti n fi ifẹ han lati se agbekalẹ abule Ruga ni ipinlẹ wọn.

Ni ipinlẹ Kano, gomina Abdullahi Ganduje ti se agbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹrindinlogun ti yoo sawari awọn agbegbe ti wọn yoo tẹ abule Ruga naa si.

Image copyright Getty Images

Bakan naa ni ipinlẹ Plateau, gomina Simon Lalong ti kede pe gbagbagba ni oun n se atilẹyin fun agbekalẹ abule Ruga nitori igbesẹ naa yoo mu opin de ba aawọ to maa n fi ojoojumọ waye laarin awọn agbẹ ati darandaran yika orilẹede yii.

Ni Bauchi, Bala Muhammad tii se gomina ibẹ naa ti salaye pe, gbogbo ara ni oun fi n ti agbekalẹ abule Ruga lẹyin nitori ida aadọrin ninu ọgọrun awọn olugbe ipinlẹ Bauchi lo jẹ Fulani darandaran.

Ijọba ipinlẹ Niger naa, lati ipasẹ akọwe ijọba ipinlẹ ọhun, Ahmed Matane ti kede pe ko iyatọ laarin ibudo ifẹranjẹ ati abule Ruga, awọn alanikanjọpọn kan lo kan fẹ lo lati da wahala silẹ ni Naijiria.

Image copyright Getty Images

Awọn ipinlẹ yoku to si ti tun kede atilẹyin wsn fun agbekalẹ abule Ruga ni iwọnyii:

 • Gombe
 • Taraba
 • Adamawa
 • Kaduna
 • Sokoto
 • Nassarawa
 • Kaduna
 • Zamfara
 • Kebbi
 • Katsina ati
 • Kogi.

Ijọba apapọ si ti sọ saaju pe agbekalẹ abule Ruga yoo jẹ ki imọtoto to yẹ wa fawọn ẹran ta n jẹ nilẹ Naijiria.