Òwe Yorùbá: Mélòó lo lè parí nínú òwe Yorùbá yìí?

Aworan to n sọ itan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aworan to n sọ itan

Ọpọ ọmọ Yoruba lo maa n leri pe awọn dantọ ninu imọ ijinlẹ ede Yoruba ati nipa aṣa ibilẹ wa.

Lara ohun ti eeyan le fi danrawo boya lootọ ni aayan mọ ijinlẹ ede Yoruba niyii, a ti ṣe akojọpọ diẹ lara awọn òwe ti BBC Yorùbá ti lò sẹyin fun yin.

Bi o ba wa da ọ loju pe o mọ owe Yoruba, tẹ ibi yii ki o dahun bi o ṣe yẹ.

O ni anfani lati wo maaki rẹ bi o ba ṣe tan.

  • Adé orí ọ̀kín kò lè ṣe déédé orí ẹyẹkẹ́yẹ
  • Àgbàdo inú ìgò, ó di àwòmọ́jú fún adìyẹ
  • Pẹ́pẹ́yẹ ńlérí lásán ni, kò ní kọ
  • A kì í dàgbà jù fún ohun tí a kò bá mọ̀
  • Kíkéré l'abẹ́rẹ́ kéré, kì í ṣe mímì fún adìyẹ
  • Ó di ìgbà tí òjò bá dá kí alágborùn tó mọ̀ pé ẹrù lòún gbé
  • Dídákẹ́ lerín dákẹ́ àjànàkú ló lẹgàn
  • Adẹ́tẹ̀ ò lè fún wàrà ṣùgbọ́n ó lè da wàrà nù
  • Àdánìkànrìn ejò ló ńjẹ ọmọ ejò níyà
  • Tí ẹja bá sùn ẹja á fi ẹja jẹ.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si