Conjoined Twins: Kìí ṣe ìdájọ́ ikú ṣùgbọ́n gbígbé ayé á nira

Conjoined Twins: Kìí ṣe ìdájọ́ ikú ṣùgbọ́n gbígbé ayé á nira

Àṣìṣe kan lè ba ohun gbogbo jẹ́ gẹgẹ bi dokita ṣe sọ ọ.

Sarfa ati Mawa kò rí ara wọn rí ṣaaju iṣẹ abẹ pataki yii ṣugbọn ireti wa lọkan awọn obi wọn pe iṣẹ abẹ lati ya wọn sọtọ naa yoo yọri si rere.

Dokita ni ọpọlọ awọn mejeeji n ṣiṣẹ funrawọn sugbọn lati ya wọn, wọ́n á kọ́kọ́ pín àwọn ẹ̀jẹ̀ tó so mọ́ ọpọlọ.

Lẹyin naa ni ọpọlọpọ igbesẹ yoo tẹle e ni ilana to tọ ko ma baa si aṣiṣe.

Nigba ti Ọlọrun ṣaami si adura wọn to gba ọwọ awọn Dokita ṣiṣẹ tan, ayọ gbogbo wọn ko lonka.

Inu iya wọn Zainab Bibi dun, o ni ala oun ti wa si imuṣẹ bayii tori oun le maa gbe wọn ni kọọkan.

Iṣẹ́ ni àwọn dókítà ṣe o kí àwọn ọmọ naa to ni iwosan pipe.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si