Osun: Gboyega Oyetola, Adeleke ń ṣe àríyànjiyàn lórí èyí tó dárajù nínú 'oníjó' àti 'akówójẹ'

Adeleke ati Oyetọla Image copyright dailypost

Ọrọ naa bẹrẹ pẹlu gomina Gboyega Oyetola to ni inu oun bajẹ gidigidi wi pe onijo lo ba oun du ipo gomina ipinlẹ Oṣun lasiko idibo gomina to waye lọdun 2018.

Oyetola sọrọ yii lasiko to gbalejo awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu SDP to wa ki i ni ile ijoba nilu Osogbo.

Oyetọla ni aikun oju iwọn eto idibo orilẹede Naijiria lori yiyan awọn oludije lo fun iru awọn eeyan bi Adeleke lanfani lati dije tako oun.

Ẹ jẹ ki a wo bi o ṣe sọọ gan ni ẹkunrẹrẹ:

"Ọpọ igba ti mo ba joko ti mo si ronu lọ sori pe iru Adeleke, to jẹ pe ijo jijo nikan lo ti jafafa, ni mo n ba dije du ipo gomina, ara mi a si bu maṣọ, oju ara mi a si gba mi ti. Ajalu nla nii ba jẹ fun ipinlẹ wa ka ni ọna miran lọrọ yii ba yọ ni."

Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington

Supreme Court : Oyetola fẹ̀yìn Adeleke janlẹ̀ nílé ẹjọ́ tó ga jù lọ!

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYinka Ayefele: Oṣù àwọn ìbẹ́ta mi kò pé ní kò jẹ́ kí n kọ́kọ́ kéde ìbí wọn

Amoṣa ki ni Sẹnetọ Ademola Adeleke to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko idibo naa gbọ eyi si, o ni wọn ko gbe ẹnu toun naa fun alagbafọ.

Oun pẹlu wa fi gbolohun diẹ ṣọwọ si Gomina Oyetọla pe oun dupẹ toun o pe oun jẹ onijo, ṣugbọn ijo jijo kii ṣe aisan. Koda o tun tẹsiwaju, O ni o san fun oun lati jẹ onijo ki oun si fi ays inu oun han ju ki oun maa "po ẹkọ ibinujẹ ati wahala faraalu nipa lilu aṣuwọn owo ilu ni ponpo."

Adeleke ni ọpọlọpọ ere lo n bẹ ninu ijo jijo. Nigba ti yoo parí ọrọ rẹ, Sẹnetọ Adeleke ni..."ijo jijo san ju ka lu owo ilu ni ponpo lọ"

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdeleke fọhùn, 'èmi ni gómìnà tí wọ́n dìbò yàn'

O wa ranṣẹ ọrọ si Oyetọla pe, "Jẹ ki n ran Oyetọla leti pe iwe rẹ gẹgẹ bii olori awọn oṣiṣẹ fun Rauf Arẹgbẹṣọla fihan gbangba peko kun oju iwọn gẹgẹ bii alakoso, ṣugbọn o jafafa ninu ka lu owo ilu ni ponpo."

Ọrọ yii ti n ja ranyinranyin laarin awọn ololufẹ igun mejeeji at'awọn onwoye. Bi awọn kan ṣe n wi pe o yẹ ki awon mejeeji o ṣọra pẹlu ọrọ wọn gẹgẹ bíi opomulero ni ipinlẹ naa l'awọn kan n jiyan lori ọrọ mejeeji.