Delta Building Colapse: Ilé wó lu ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ní Abraka

Ile to wo pa awọn ni Nairobi Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Ile wiwo

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni wi pe ile alaja mẹta kan ti wọn n kọ lọwọ ni ijọba ibilẹ Ethiope East, ipinlẹ Delta ti wo lulẹ.

Gẹgẹ bi alukoro ile iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Delta ṣe ṣalaye fun akọroyin BBC, Onovwakpoyeya Onome sọ pe lootọ ni o ṣẹlẹ ni agbegbe Abraka.

Bi o tilẹ jẹ wi pe a ko tii le fi aridaju ohun to ṣokunfa ile wiwo naa, iroyin sọ pe lasiko ti ojo n rọ lo ṣẹlẹ lowurọ ọjọ abamẹta.

Bakan naa ni iroyin ọhun sọ pe awọn eniyan n duro ki ojo to n rọ da labẹ ile naa ni afi to di wọ̀ọ̀ nilẹ.

Oniruuru ni iroyin to ti n jade lati ṣapejuwe ohun to ṣẹlẹ gan ati iru ile ti o jẹ.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ wa fun yin bi a ba ti ri aridaju ohun gbogbo.