Osinbajo: Ààrẹ Buhari rán mi láti wá àbáyọ sí ààbò tó mẹ́hẹ

Oba Babatunde Ajayi, ati Awujale ti ilu Ijebu, Oba Sikiru Adetona, Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń jíròrò láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Naijiria, pàápàá ní Ìwọ-òòrùn Naijiria.

Igbakeji Aarẹ Orilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo ti se ipade pọ pẹlu Akarigbo ti ilu Remo, Oba Babatunde Ajayi, ati Awujale ti ilu Ijebu, Oba Sikiru Adetona, lori eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Osinbajo, lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ pẹlu gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun sọ wi pe, Aarẹ Buhari lo ran oun wa lati wa ọna abayọ si ipenija eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn ọba mejeeji naa ti fun oun ni imọran lori ọna ti awọn le gba, lati mu ki eto aabo gbooro si kaakiri awọn agbegbe to wa lorilẹede Naijiria.

Image copyright Yemi osinbajo

Amọ, Osinbajo fikun wi pe, awọn asebajẹ kan ni awujọ n wa ọna lati fi ọrọ eto abo to mẹhẹ naa lati da Naijiria ru.

Bakan naa, ni Igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo naa fikun un wi pe, awọn yoo sepade pẹlu awọn ọba to ku nitori awọn mọ wi pe, awọn lo sun mọ awọn ara ilu julọ.