Abúlé tí wọn kìí ti sọ ọmọ ní orúkọ, ohùn arò ni wọ́n fi ń pè wọ́n
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kong Thong: Àwọn òbí máa ń súfèé kọrin tàbí hu láti pe ọmọ tó bá dàgbà

Ara meeriri ree o, a ri ori ologbo lori atẹ, airin jinna si ni airi abule ọkẹrẹ, bi eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.

Idalu ni iṣelu, bi a ti n ṣe ni ile wa, eewọ ibomiran si ni si ni Yoruba maa n wi.

Bẹẹ ni ọrọ naa ri pẹlu abule kan ni orilẹede India, ti wọn n pe ni Kong Thong, to wa nilu Meghalaya.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni abule yii, ẹ ro pe iya àti baba ọmọ n ṣun ẹkun ni, lasiko ti wọn ba n fi ohun aro pe ọmọ wọn.

Bakan naa, awọn obi yii maa n sufe kọrin fun awọn ọmọ wọn ni, ti wọn si maa n hu lati pe awọn ọmọ to ti dagba.