Coza Rape: Ọlọ́pàá ránṣẹ́ pe Timi Dakolo àti ìyàwó rẹ̀ lórí ẹ̀ṣùn ìfipábánilòpọ̀

Timi dakolo ati iyawo rẹ, Busọla Image copyright @timidakolo

Ileesẹ ọlọpaa ti ti ẹsẹ ofin wọ ẹsun ifipabanilopọkan ti Timi Dakolo ati Busọla iyawo rẹ fi kan Pasitọ kan nilu Abuja, Tolu Fatoyinbo.

Lọwọlọwọ bayii, ileesẹ ọlọpaa ti ransẹ pe tọkọtaya naa pe ki wọn yọju si ilu Abuja, lọdọ ọga ọlọpa kan, Ibrahim Agu fun ifọrọwanilẹnuwo.

Iwe ipe awọn ọlọpaa yii, ti igbakeji Kọmisọna ọlọpaa lolu ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa nilu Abuja, Kolo Yusuf fọwọsi, lo pasẹ fun tọkọtaya naa lati yọju si wọn lọjọ Iṣẹgun to n bọ, eyiun ọjọ Kẹtalelogun osu Keje ọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara ohun ti awọn ọlọpaa kọ sinu iwe ipe ọhun ni pe " ileesẹ naa fẹ tanna wadi ẹsun lilẹdi apo pọ lati huwa ọdaran, irọ pipa, etekete ati idunkooko mọ ẹmi ẹni, ninu eyi ti wọn ti darukọ yin. "

"A si fẹ kẹ yọju si osisẹ ọlọpaa to fọwọsi lẹta yii ni lọjọ Iṣẹgun to n bọ, eyiun ọjọ Kẹtalelogun, osu Keje, ọdun 2019 ni aago mẹwa owurọ ki Ibrahim Agu le e wadi ohun gbogbo daju, ko si fi idi eyi tii se otitọ mulẹ."

Bẹẹ ba agbagbe, laipẹ yii ni ariwo sọ nigba ti Busọla sọ lori fọnran aworan kan pe Pasitọ Fatoyinbo ti ijọ COZA fi tipa ba oun ni ajọsepọ lọdun mẹrindinlogun sẹyin nilu Ilọrin lasiko ti oun si wa ni ọdọ.

Nibayii na, ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa ti kede pe lootọ ni oun fi lẹta sita lati ransẹ pe tọkọtaya Dakolo lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn kede nijooni.

Atẹjade kan ti ileesẹ ọlọpaa fisita loju opo Twitter rẹ salaye pe, eyi ko tumọ̀ si pe wọn fẹ́ ti tọkọtaya naa mọle ni, amọ o jẹ ara ohun eelo iwadi lati tan imọlẹ si ẹsunkẹsun tawọn eeyan ba gbe wa siwaju awọn.

Image copyright AFP

Mba wa rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati gba alaafia laaye, nitori ileesẹ ọlọpaa ko ni segbe sẹyin igun kankan amọ yoo ri daju pe idajọ ododo fẹsẹ mulẹ lori isẹlẹ naa.

Amọ nigba to n fesi si iwe ipe ileesẹ ọlọpaa naa ati ọrọ to wa ninu rẹ, Timi Dakolo sọ loju opo Instagram rẹ pe igbesẹ naa ko ba awọn lojiji nitori agbẹjọro awọn ti sin awọn ni gbẹrẹ ipakọ tẹlẹ pe iru isẹlẹ naa le waye.

O ni ti eeyan ba ronu jinlẹ lori ọrọ to wa ninu iwe ipe awọn ọlọpaa naa, o fihan pe esuro ti n padi da, maa le aja lori ẹsun ifipabanilopọ naa, tawọn ọlọpaa si ti fẹ fi ẹsun irọ pipa ati ibanilorukọjẹ we oun ati iyawo oun lọrun.