Federal Cabinet: Onímọ̀ ní ewu ń bẹ lórí bí ìsàkóso ìjọba ṣe dúró rigidi

Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright @MBuhari

Awọn onimọ nipa ọrọ aje ti mu igbe bọnu pe, ewu n bẹ loko Longẹ fun orilẹede Naijiria, to si seese ki ọrọ aje tun dagun lẹẹkan si ti aarẹ Muhammadu Buhari ko ba tete kede awọn ọmọ igbimọ alasẹ rẹ.

Koda, n se ni wọn n gbarata pe eto isakoso ijọba apapọ ti duro soju kan soso ju, o si yẹ ki Buhari tete mọ odo ti yoo da ọrunla si nipa yiyan awọn minisita ti yoo ba sisẹ.

Lero tawọn onimọ ọrọ aje yii, Buhari gbọdọ tete ta mọra lati fi orukọ awọn minisita rẹ sọwọ sile asofin apapọ, ki wọn to lọ fun isinmi, bi bẹẹ kọ, ọfọn lee fi iru nagba nidi ọrọ aje wa, kawọn asofin naa to pada de.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni wsn tun n kọminu pe ti orukọ awọn minisita naa ba tiẹ de siwaju ile asofin apapọ lọsẹ yii, n jẹ asọ si lee ba ọmọyẹ mọ, nidi ikede awọn tile asofin ba fi ontẹ lu ninu wọn.

Awọn onimọ naa ni diẹ ni ti Alaba lọrọ ibeji taa ba n sọrọ eto isakoso ati awọn osisẹ ọba nitori iwọnba ni wọn lee si, ọpọ asẹ si lo wa lọwọ awọn minisita ti yoo ba aarẹ sisẹ.

Image copyright @nassnigeria

Wọn tun woye pe, lọwọlọwọ bayii, idaduro to wa nidi yiyan awọn minisita ti n se akoba bayii fun eto ọrọ aje wa, ti Buhari ko ba si gbe igbesẹ lori rẹ ki awọn asofin to gba isinmi, eyi lee paroko ti ko dara ransẹ si awọn eeyan to fk wa dokowo sorilẹede yii lati ilẹ okeere.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ kẹtalelogun osu Keji ọdun 2019 ni wsn ti seto idibo aarẹ, ti wsn si kede Buhari lẹyin ọjọ diẹ, ti eto ibura fun saa keji rẹ si waye lọjọ Kọkandinlọgbọn osu Karun ọdun 2019.

Ireti awọn ọmọ Naijiria ni pe ko yẹ ko si ohunkohun ti yoo maa da aarẹ lọwọkọ mọ lati yan awọn ọmọ igbimọ alasẹ rẹ, ki eto isejọba lee tẹsiwaju laisi idaduro rara.