SERAP: SERAP gbé ìjọba Nàìjíríà lọ iléẹjọ́ ọ̀daràn lágbàáyé, ICC

Awọn ọmọde ti ko lọ sile ẹkọ Image copyright @Danjauro

Ajọ SERAP ti gbe awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Naijria lati ọdun 1999 di isinsinyi lọ sile ẹjọ agbaye, ICC to n gbẹjọ iwa ọdaran, lori ẹsun pe wọn ko jẹ ki awọn ọmọde to le ni miliọnu mẹtala lanfani si eto ẹkọ.

Ajọ SERAP fi iwe ipẹjọ ṣọwọ si oludari igbimọ igbẹjọ nile ẹjọ ọhun, arabinrin Fatou Bensouda, lati lo ofiisi rẹ fi ṣe iwadii idi abajọ ti ọgọrọ ọmọde ko ṣe lanfani lati lọ sile ẹkọ.

Bakan naa, ajọ SERAP tun rọ Bensouda lati ṣewadi ikuna ijọba Naijiria fun ọpọlọpọ ọdun, lati wa nnkan ṣe si ọrọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajọ SERAP ni eyi tumọ si iwa ipa ati iwa ọdaran si awọn ọmọde.

Ajọ naa tun rọ ileẹjọ ICC lati kan si awọn aarẹ ati gomina ti to ṣe ijọba Naijiria tẹlẹ ri lati ọdun 1999, ati awọn to wa lori aleefa lọwọlọwọ lori ọrọ ọhun.

Image copyright AFP

SERAP ni, ọpọ ọmọde lo ti ku iku aitọjọ, ti ọpọ si wa ninu ewu nla nitori aisi nile iwe, eyi to jẹ ikuna ijọba ni Naijiria.

Ajọ naa fidi rẹ mulẹ pe, ileẹjọ ICC ti ṣalaye tẹlẹ pe iwa ọdaran ni ki awọn ọmọde maa lanfani si ile ẹkọ.

SERAP tun rọ ileẹjọ ICC lati kan an nipa fun awọn alaṣẹ ijọba Naijiria lati rii wi pe, ọgọọrọ awọn ọmọde ti ko si nile iwe lanfani lati pada sile ẹkọ.