Kwara Kidnap: Ọlọ́pàá láwọn yóò wá àwọn ọmọ ilẹ̀ Turkey mẹ́rin tí wọ́n jígbé rí láàyè

Kayode Egbetokun Image copyright Facebook/Kayode Egbetokun

Ile ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti wọ igbo lọ lati doola ẹmi awọn ọmọ orilẹede Turkey mẹrin tawọn agbẹbọn mẹfa kan jigbe lalẹ ọjọ Abamẹta nibi ti wọn ti gbafẹ ni igberiko kan ti wọn ni Gbale.

Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Kwara, Ajayi Okasanmi to ba BBC Yoruba sọrọ, ni awọn agbofinro yoo wa awọn ọmọ ilẹ Turkey naa ri laaye.

Orukọ awọn mẹrin ti wọn jigbe ọun ni Seyit Keklik, Yasin Colak, Ergun Yurdakul, ati Senerapal.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYinka Ayefele: Oṣù àwọn ìbẹ́ta mi kò pé ní kò jẹ́ kí n kọ́kọ́ kéde ìbí wọn

Okasanmi ṣalaye pe kete ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Kayode Egbetokun paṣẹ fawọn ọlọpaa kogberegbe, Operation Puff Adder pe ki wọn bẹrẹ si wa awọn ọmọ ilu okere naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa tun sọ pe gbogbo agbara ti ile iṣẹ ọlọpaa ni lawọn agbofinro yoo fi wa awọn ti wọn jigbe ọun.

Ọgbẹni Okasanmi sọ pe laipẹ laijina, ọwọ awọn ọlọpaa yoo tẹ awọn agbebọn mẹfa ọun.