Buhari yóò rí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà yóò sì gbìmọ̀ràn sáà kẹta nípò-Dele Momodu

Odu oniroyin ni Dele Momodu ti ẹnikẹni ko le jiyan lori iduro rẹ gẹgẹ bi ajafẹtọ araalu pẹlu.

Amọṣa lasiko idibo apapọ to kọja, ọpọ awọn ọmọ orilẹede yii paapaajulọ awọn to jẹ alatilẹyin Aarẹ Muhammadu Buhari ni wọn kọju ija sii lori ọpọ oju opo ayelujara wi pe o n tẹle oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko idibo naa, oloye Atiku Abubakar.

Bi o tilẹ jẹ wi pe idibo apapọ ti lọ, sibẹ Dele Mọmọdu ni ironu awọn eeyan to wa nidi eyi ba oun ninu jẹ lọpọlọpọ, o si mu ẹnu le alaye ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu BBC News Yoruba.