Lórí ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ COZA àti Dakolo, Ìwadìí ń tẹ̀ síwájú, ṣùgbọ́n a kò mọ ohunkohun nípa rẹ̀ mọ́- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Èkó

Timi Daloko ati Busọla iyawo rẹ Image copyright @Timidakolo

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ni awọn ko mọ ohunkohun mọ nipa ẹjọ ẹsun ifipabanilopo ti iyawo gbajugbaja olorin Timi Dakolo, Busọla, pe tako Pasitọ Fatoyinbo.

Gẹgẹ bii alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Bala Elkana ṣe sọ fun BBC News Yoruba, wọn ti ko iwe ẹjọ naa lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, nilu Abuja nibi ti iwadii naa ti n tẹ siwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé

Amọṣa nigba ti a pe alukoro apapọ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria lori ẹrọ ibanisọrọ, a ko rii ba sọrọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFathia Balogun: Kò sí ẹni tó bá mi lò pọ̀, kó tó fún mi ní isẹ́

Ni opin ọsẹ to kọja ni Timi Dakolo ke ibosi sita pe lẹyin ọpọlọpọ ọsẹ ti awọn ti fi iwe ipẹjọ siwaju ileeṣẹ ọlọpaa, awọn ko tii gbọ pe wọn ti pe iranṣẹ Ọlọrun naa fun ifọrọwanilẹnuwo.