Nigeria Air Force: Mo mọ̀ọ́mọ̀ dá €37,000 ti mo rí he padà ni -Ọmọ ogun Bashir

Image copyright Nigeria Air Force
Àkọlé àwòrán O wu mi lati jẹ awokọṣe rere ni

Omo ogun ofurufu Naijiria, Bashir Umar ni o ri owo nla tilẹ okeere he ni papakọ ofurufu ti Kano.

Bashir ri owó pọun ẹgbẹrun mẹtadinlogoji he ni eyi to to miliọnu mejila naira lasiko ti o n ṣọde ninu apo kan.

Omo ogun ofurufu Bashir Umar ni oṣiṣẹ alaabo to wa lẹnu iṣẹ lasiko ti ẹnikan gbagbe owo naa silẹ pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ..

O wa pe nọmba to wa lara apo owo naa ki o fi ba ẹni to ni owo naa sọrọ lati wa gba owo rẹ pada.

Oga agba Sadique Abubakar to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun ofurufu ti Naijiria ti paṣẹ eto idanilọla fun olootọ ọmọ ogun yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAjọ SERAP sọrọ lori owo ifẹhinti awọn oloselu kan

Ogagun Sadique ni ki olori ẹka aato ileeṣẹ ologun ofurufu, Kingsley Lar bẹrẹ igbesẹ lori eto idanilọla naa.

O ni eto akanṣe yii yoo jẹ iwuri ati koriya fawọn ọdọ Naijiria nipa ootọ inu ati iwa ọmọluwabi to ti n sọnu lawujọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEjo abami to n mu owo ni ajọ Jambu

Ninu ọrọ Lar to nmojuto eto idanilọla fun Bashir Umar lo ti ni ootọ inu ati iwa ọmọluwabi jẹ ọkan gboogi lára abuda adamọ ọmọ ogun ofurufu rere.

Eyi kii ṣe igba akọkọ ti iru iwa akin bayii maa ṣẹlẹ ni Naijiria.

Loṣu kẹjọ ọdun to kọja ni awọn alaṣẹ ṣeto idanilọla nipinlẹ Eko fun awọn oṣiṣẹ eleto aabo meji ti wọn da owo gọbọi ti wọn ri he pada ati awọn ohun eelo olowo iyebiye mii.

Awọn oṣiṣẹ mejeeji yii da awọn apo yii pada ni ibudo ti wọn ti ri wọn he.

Inu ọmọ ogun Bashir dùn lati ṣe ohun ti o tọ nipa jijẹ awokọṣe rere fun awọn ọdọ Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDele Momodu : Lẹ́yìn Buhari àti Atiku, èrò ọjà làwọn olùdíje yóòkù ní ìdìbò 2019