Ìkọlù Shiite àti ọlọ́pàá
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹ̀mí sùn níbi ìkọlù Shiite àti ọlọ́pàá

Ẹgbẹ shiitee sọ pe ọmọ ẹgbẹ awọn mọkanla lo gbẹmi mi ti ọpọ eeyan si farapa nibi ikọlu to waye laarin ẹgbẹ naa atawọn ọlọpaa lọjọ Aje loluulu orilẹede Naijiria, Abuja.

Ẹgbẹ n fẹhonu han nitori olori wọn to wa latimọle, Ibrahim Zakzaky, ohun ti wọn n beere fun ni pe ki ijọba fun un lominira.

Iroyin kan tẹ sọ pe ọga ọlọpaa kan naa tẹri gbaṣọ nibi iṣẹlẹ ọhun ṣugbọn ile isẹ ọlọpaa ko tii fidii ọrọ naa mulẹ.