Ibadan: Òkìtì iyanrìn wó pa Wale àti Adeyemi lágbègbè Ologuneru

Osi akoyanrin kan nibi iṣẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn miran pẹlu fi ara ṣeṣe ninu iṣẹlẹ naa.

Ibudo ìwa iyanrin ni ilu Ibadan ni ipinlẹ Oyo ni iṣẹlẹ laabi ọhun ti waye.

Eeyan meji to n ṣiṣẹ ni ibudo iwayanrin kan nilu Ibadan ti di oloogbe bayii.

Iku wọn ko si ṣẹyin bi okiti yanrin ti wọn n wà ṣe da wo lu wọn ni ibi ti wọn ti n wa yanrin si ọkọ lagbegbe Ologunẹru ni ilu Ibadan.

Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣe sọ, okiti iyanrin naa ti wọn ni o fẹrẹ ga to ile alaja meji ṣa deede da wo ni ti o si bo awọn eeyan mẹta ti wọn wa ni isalẹ rẹ mọlẹ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn aladugbo sọ pe ko din ni eeyan meje to ba isẹlẹ naa lọ.

Wọn ni 'awọn mẹta ni yanrin naa bo mọlẹ, awọn mẹta miran n ko yanrin ọhun si inu ọkọ akẹru lasiko ti ijamba yii ṣẹlẹ".

Awọn oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo to wa nibi iṣẹlẹ naa ni eeyan meji lo ku ninu iṣẹlẹ naa ṣugbọn awọn miran fi ara pa.