UK Prime Minister: Boris Johnson, Olóòtú ìjọba Gẹ̀ẹ́sì tuntun sọ̀rọ̀ àkọ́kọ́

Àkọlé àwòrán Jeremy Hunt ti ki Boris Johnson ku oriire

Boris Johnson ati Jeremy Hunt ni wọn jọ dije igbẹyin ninu eto idibo ọhun.

Kete ti wọn kede Boris Johnson ni ẹni to jawe olubori ninu ibo naa ni Jeremy Hunt ti kii ku oriire pe:

Jeremy sọrọ lori iṣẹ ipolongo takuntakun ti awọn mejeeji jó ṣe ni eyi to yẹ ko jẹ awokọṣe fawọn oludije miran.

Alatako Boris Johnson ni oun gbagbọ pe iṣẹ akinkanju ti ko ni ja ilẹ Gẹẹsi kulẹ ni Boris a ṣe ni orilẹ-ede wọn.

Nigba ti Boris Johnson ṣàpèjúwe alátakò rẹ̀ bíi ọlọ́pọlọ pípé ninu ọrọ akọsọ rẹ, bẹẹ naa lo fimoore han fun gbogbo eniyan pe:

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti kede ẹni to jawe olubori ninu ibo Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi ti wọn di lọjọ Isẹgun.

Oluwarẹ ni Boris Johnson.

Jeremy Hunt ni òun gbà pé Boris Johnson á ṣiṣẹ́ dáadáa

Ibo ẹgbẹrun lọna mejilelaadọrun ati mẹtalelaadọjọ ni Johnson ni ninu apapọ ibo ti wọn di nigba ti alatako rẹ, Jeremy Hunt ni ibo ẹgbẹrun lọna mẹrindinlaadọta, ẹgbẹta ati mẹrindinlọgọta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni kete ti wọn kede esi ibo naa ni Johnson ti yonbo alatako rẹ ti wọn dijọ fa ipo naa mọ ara wọn lọwọ, eyiun Jeremy Hunt, to si se apejuwe rẹ bii ẹni to kun fun ọpọ ọgbọn to dara.

Johnson wa seleri pe oun yoo ji mu ninu awọn ero ọgbọn alatako oun naa, to si kun kan saara si olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi ana, Theresa May fun bo se sisẹ sin orilẹ-ede rẹ.

Ninu ọrọ akọsọ rẹ, Johnson fikun pe inu oun dun lati sisẹ ninu isejọba Theresa May, toun si ri itara rẹ ati ipinnu to ni si ọpọ igbesẹ rẹ naa, eyi to di ogun to fi silẹ bayii.

Bakan naa lo salaye pe, oun mọ pe awọn eeyan yoo maa beere idi ti wọn se yan oun ni olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, to si dahun pe ko si ẹnikẹni tabi ẹgbẹ oselu kankan to da nikan ni ọgbọn tara rẹ.

Related Topics