Ìtàn Mánigbàgbé: Ìtàn Adegbọrọ kọ́ wa láti ṣiṣẹ́ kára pẹ̀lú ìforítì

Alabaru to n ti ọmọlanke Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìtàn tó rọ̀ mọ́ òwe "Ẹni tí kò ṣe bíi aláàárù l'Oyingbo...

Ọpọ ọmọ ilẹ Yoruba lo maa n tiraka lati ri ti aje se, ti ara wọn kii si balẹ ti buruji ko ba si lọwọ wọn.

Wọn maa n ti ilu kan lọ si ekeji lati wa ti aje ṣe, ti ọpọ ajeji si maa n di ọmọ onilu lẹyin o rẹyin nigba ti Ọba oke ba bukun wọn.

Sugbọn nigba miran, ọpọ ọmọ Yoruba to ba wa isẹ aje lọ silu miran kii gbagbe ile nitori igbagbọ wọn ni pe ọmọ to ba sọ ile nu, o so apo iya kọ.

Koda, wọn a maa figba gbogbo ranti pe ko si ibi to dabi ile.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ lọrọ ri pẹlu ọkunrin kan ti wọn n pe ni Adegbọrọ to n gbe ni ilu Ibadan.

Lasiko ti nnkan le koko fun Adegbọrọ, ti ko ri ba tise, ti ko ri ọna gbegba, ti isẹ n sẹ ẹ gidi, lo ba ronu jinlẹ lori ọna abayọ si ipọnju to ba a yii.

Adegbọrọ di igba ati agbọn rẹ, to si gba ilu Eko lọ lati wa isẹ Aje ṣe, ko le e riba ti se, ko si ri ọna gbegba.

Nigba to de ilu Eko, ọja Oyingbo lo balẹ si, to si n sisẹ alabaru nibẹ, bo se n fi ori rẹ gbe apo ata, lo n gbe apo ẹwa, irẹsi, apo elubọ, Sẹmo, agbado ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìtàn Mánigbàgbé: Ìtàn Adegbọrọ kọ́ wa láti ṣiṣẹ́ kára pẹ̀lú ìforítì

Nigba to ya, pẹlu aforiti ati iṣẹ aṣekara, to si mọ baa ṣe n pọn omi silẹ de oungbẹ, Adegbọrọ fi owo pamọ, to si ra ọmọlanke lati maa fi ṣe aaru dipo ori to fi n ru ẹru.

Bakan naa ni eyi yoo mu ki owo to n pa wọle ru gọgọ si.

Laipẹ laijinna, Ọba oke bukun Adegbọrọ, to si ra ọmọlanke bii meje kun eyi to ni.

Awọn ọmọlanke naa si lo fi n haya fun awọn alabaru miran lati maa sisẹ.

Ọjọ n gun ori ọjọ, osu n gori osu, Adegbọrọ lo ọdun mẹjọ ni sja Oyingbo, to si di gbajumọ nidi isẹ wiwa ọmọlanke.

Asiko yii si lo ra ọkọ akẹru to si lọ kọ ọkọ wiwa.

Adegbọrọ n mojuto isẹ ara rẹ funra ara rẹ, ti ko si fi ọwọ mẹwẹẹwa jẹun.

Nigba ti yoo si fi lo ọdun mẹrin nidi fifi ọkọ ko ẹru, Adegbọrọ tun ra ọkọ akẹru mẹfa sii, eyi to tun gba awọn awakọ si lati maa fi bawọn eeyan ko ẹru.

Nigba to ya, Adegbọrọ ranti pe ile ni abọsinmi oko, to si gba ilu Ibadan, tii se ilu abinibi rẹ lọ lati kọ ile. Ile awodamiẹnu, ile awosifila si ni Adegbọrọ kọ si adugbo ọja Ọba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìtàn Mánigbàgbé: Ìtàn Adegbọrọ kọ́ wa láti ṣiṣẹ́ kára pẹ̀lú ìforítì

Asiko yii ni irawọ Adegbọrọ bẹrẹ si ni tan, ti ogo rẹ n bu yọ nilu Ibada.

Ọpọ eeyan si n tọ ọ wa pe ko sọ asiri owo rẹ fun awọn nitori awọn naa fẹ dabi rẹ, se aye ki bani ri wahala ẹni, sokoto to balẹ nikan ni ọmọ araye n ri.

Adegbọrọ wa da wọn lohun pe ti wọn ba fẹ lowo, ki awọn naa kalọ si ọja Oyingbo.

Ki wọn wa fi ori ru aaru, amọ ọpọ wọn lo fi ọwọ osi ta ika oṣi danu pe, laalae, awọn ko le e ṣiṣẹ aaru gbigba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìtàn tó rọ̀ mọ́ òwe "Ẹni tí kò ṣe bíi aláàárù l'Oyingbo...

Idi si re e ti Adegbọrọ naa fi maa n da wọn lohun pe:

"Ẹni ti ko ba ṣe bii alaaru l'Oyingbo, ko lee ṣe bii Adegbọrọ l'ọja Ọba".

Eyi to tumọ si pe, ikoko ti yoo jẹ ata, idi rẹ yoo kọkọ gbona, ti a ko ba si jiya to kun agbọn, eeyan ko ni jẹ aye to kun aha.

Awọn ẹkọ ti itan Adegbọrọ kọ wa:

  • Itan Adegbọrọ kọ wa lati maa ni iforiti
  • O kọ wa lati maa tẹpamọsẹ
  • A kọ ọgbọn lati maa ni ajẹsẹku, ka si mase maa fi ọwọ mẹwẹẹwa jẹun
  • O tun n ran wa leti pe ka mase gbagbe ile ta ba wa ni ajo
  • Itan naa tun kọ wa pe ipokipo ta ba wa, ka maa wọna bii a se ni igbega kuro nibẹ.