Jakande: Osinbajo, Tinubu, Osoba kọwọrin lọ ki Jakande ọlọ́jọ́ ìbí

Yemi Osinbajo n dari gige akara oyinbo fun Jakande Image copyright @followlasg
Àkọlé àwòrán Jakande: Osinbajo, Tinubu, Osoba kọwọrin lọ ki Jakande ọlọ́jọ́ ìbí

Yoruba ni ti ọmọ ọni ba dara, o yẹ ka wi, ti pe a fẹ fi se aya kọ.

Eyi lo mu ki awọn ilumọọka oloselu, awọn akọsẹmọsẹ ati awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ fi n kọrin re ki gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, Lateef Kayọde Jakande, ẹni to pe ẹni aadọrun ọdun loke eepẹ lọjọ Isẹgun.

Igbakeji aarẹ Yẹmi Ọsinbajo, to bawọn peju sibi ayẹyẹ naa to waye nilu Eko, sapejuwe ọlọjọ ibi naa gẹgẹ bii akikanju to maa n mu ayipada rere ba nkan ninu itan eto iselu orilẹede yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Osinbajo ni pẹlu oju inu ati ọgbọn atinuda Jakande lo fi mu ayipada rere ba ilana eto ẹkọ nipinlẹ Eko lasiko to wa ni ipo gomina, eyi to mu ki ayipada rere ba eto ẹkọ Naijria patapata, paapa bi wọn se pa eto ẹkọ ọlọsan rẹ patapata.

Image copyright @followlasg
Àkọlé àwòrán Bakan naa ni Bola Tinubu sapejuwe Lateef Jakande bii alakoso to dantọ lasiko to nira lati dari Naijiria.

Bakan naa lo fikun pe ilana ẹkọ ọfẹ ti Jakande se lo fun ọpọ ọmọ nipinlẹ Eko lanfaani lati lọ sile ẹkọ, to si tun kọ ilegbe olowo pọọku to pọ julọ ti ijọba kankan yoo kọ ri, boya ni ipinlẹ ni abi labẹ ijọba apapọ.

Ninu ọrọ tiẹ naa, Gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, Bola Ahmed Tinubu ni Jakande ni o maa n kọkọ se ohun akọkọ lasiko akoso rẹ, to si jẹ alakoso to dantọ lasiko to nira lati se adari lorilẹede Naijiria.

Image copyright @followlasg
Àkọlé àwòrán Háà, ó ṣe! Jakande pé 90 láì gba àmì ẹ̀yẹ kankan ní Nàíjíríà -Osoba

"Eeyan kan to jẹ olotitọ si oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ni Alhaji Lateef Jakande jẹ, ti ko si yapa ninu ala ati iran onitẹsiwaju ti Awolọwọ fi lelẹ.

Awọn eeyan miran to tun sọrọ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni Oloye Olusẹgun Ọṣọba, tii se gomina nipinlẹ Ogun nigba kan ri.

Ninu ọrọ rẹ, Ọsọba kede pe ohun meji lo n dun ohun nipa Jakande, akọkọ ni pe baba naa ko kọ itan kankan nipa igbesi aye rẹ silẹ, tori ko ba yaayi pupọ lati gbọ latẹnu rẹ bo se lo akoko rẹ lẹnu isẹ iroyin ati eto iselu.

Image copyright @followlasg

Gẹgẹ bo se wi, ohun keji ni pe wọn ko fi ami ẹyẹ ilẹ wa kankan da Jakande lọlka ri nigba to jẹ pe awọn eeyan lasan ti ko to nidi aseyọri ti gba ami ẹyẹ orilẹede yii.

"Mo wa n daba pe ki wọn tete fi ami ẹyẹ da Jakande lọla, wọn ko si gbọdọ fun ni ami ẹyẹ to kere si Commander of the Federal Republic."

Image copyright @followlasg

Gomina ipinlẹ Eko,Babajide Sanwo-Olu ninu ọrọ tiẹ ni, ilegbe oni filaati mẹrindinlẹẹdẹgbẹta ti wọn n kọ lọwọ si adugbo Igando nilu Eko, eyi ti wọn n gbero lati si losu Kẹjọ ọdun 2019 ni wọn yoo pe ni ilegbe Laeef Jakande.