Àlàyé rèé nípa bí èrùpẹ̀ ṣe wó pa òṣìṣẹ́ akóyọyọ méjì n‘Ibadan
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ibadan Accident: Èèyàn méjì kú, ẹnìkan wà nílé ìwòsàn

Ariwo nla gbalẹ kan lọsan ọjọ Aje ni adugbo Ologunẹru nilu Ibadan nigba ti erupẹ wo lu eeyan mẹta mọlẹ, ti meji si jẹ Ọlọrun nipe loju ẹsẹ.

Idi ree ti BBC Yoruba fi kan si ibi isẹlẹ naa, ta si gbọ pe ọpọ igba ni wọn ti n kilọ fun awọn ọlọkọ akoyọyọ lati dẹkun wiwa erupẹ ni ibudo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa la tun gbọ pe, ọkọ akoyọyọ ti awọn osisẹ naa gbe lọ wa erupẹ lo wo lu ọkan ninu wọn mọlẹ.