Ìwé ìrìnnà 'VISA' Amẹ́ríkà: PDP láwọn faramọ ìgbésẹ Amẹ́ríkà

ologbodiyan
Àkọlé àwòrán Awa PDP a kò lẹ́bọ lẹ́ru rara, ipinnu Amerika yii tẹ PDP lọrun

Awọn ẹgbẹ oṣelu meji to gbajumọ lorile-ede Naijiria ti n sọ ero wọn nipa igbesẹ Ilẹ Amẹrika lati fofin de fifun awọn ọmọ Naijiria kan ni iwe irinna 'Visa'.

Igbesẹ naa ti wọn kede laipẹ yi ko yọ awọn to kopa tabi ti wọn ṣe agbatẹru dida ibo Naijiria ọdun 2019 to kọja ru.

Kola Ologbondiyan to jẹ akọwe ipolongo fẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe rẹgi ni igbeṣẹ naa ba ẹgbẹ awọn lara mu nitori pe awọn ko lọwọ ninu iwa to kọdi si eto ijọba awarawa.

O ni awọn to lagbara lati dari eto idibo ati awọn ọmọ ogun bo ti ṣe wu wọn lo le máa foya pe ijiya Amẹrika yi yoo kan awọn.

''Awa o ni ibẹru kankan nipa eto ti ilẹ Amẹrika fẹ ṣe ṣugbọn awọn to fi agidi gba ipo, awọn ti wọn gun awọn eeyan lada ati lọbẹ ni Kanoni ẹru ma ma ba''

O ṣalaye pe igbeṣẹ yi jẹ oun to dun mọ awọn ninu ati pe awọn fẹ ki awọn orile-ede miran naa tẹle apẹrẹ Amerika yi.

''Amẹrika nikan kọ lo yẹ ki wọn gbe igbeṣẹ yi, ni Yuroopu ati ilẹ Gẹẹsi,awọn na ay ki wọn ṣe bẹ''

Ologbondiyan wa fi ifarajin ẹgbẹ oṣelu PDP han lati ma mu idagbasoke ba eto oṣelu ni Naijiria

Kini APC sọ?

Ninu idibo to kọja ẹgbẹ oṣelu APC lo gbegba oroke ninu idibo gbogboogbo to waye.

Gẹgẹ bi PDP awọn naa a ma saaba na ika abuku si gbẹ alatako pe awọn ni wọn wa nidi magomago tabi iwa to le mu ifasẹyin ba eto oṣelu ni Naijiria.

Image copyright Lanre Issa-Onilu
Àkọlé àwòrán Ninu idibo to kọja ẹgbẹ oṣelu APC lo gbegba oroke ninu idibo gbogboogbo to waye.

Amọ ṣa nigba ti a kan si akọwe ipolongo ẹgbẹ naa lori ẹrọ alagbeka lori ohun ti ẹgbẹ ri si igbesẹ yi,o ni ohun ko ti le fesi si bayi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDele Momodu : Lẹ́yìn Buhari àti Atiku, èrò ọjà làwọn olùdíje yóòkù ní ìdìbò 2019

Mallam Lanre Issa Onilu ṣalaye pe atẹjade ṣi ni Amerika gbe jade ati pe wọn ko tii darukọ awọn ti wọn fi ofin de lati ma gba iwe irinna lọ si Amẹrika.

O ni bayi ti ko tii si ẹkunrẹrẹ alaye, ohun ko tii le sọrọ nipa ilana tuntun naa.

Awọn woo gan an ni ọrọ yi kan?

Atẹjade ti Agbẹnusọ fun ileeṣẹ Amerika, Morgan Ortagus fi sita ni Washington lorilẹ-ede Amerika ni lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kinni ọdun ni Amerika ti n gbiyannju lati gbe igbesẹ yii.

O ni paapaa lori awọn oloṣelu ti ko fẹ ilọsiwaju eto oṣelu ni wọn ṣe fẹ gbe e.

Ilẹ Amẹrika ko gbe orukọ awọn ti ọrọ naa kan sita tabi ki wọn sọ igba ti wọn yoo fi orukọ naa sita.