Adio Atawẹwẹ: Orin Fuji ló gba iwé kíkà lọ́wọ́ mi

Sulaimon Adio Image copyright Facebook/Atawewe
Àkọlé àwòrán Atawẹwẹ

Gbajugbaju olorin Fuji, Alhaji Sulaimọn Adio Atawẹwẹ sọ pe lati igba t'oun ti gbọ́nju, oloogbe Dr Sikiru Ayinde Barrister ni akọkọ olorin Fuji.

Atawẹwẹ fọrọ yii lede ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba nile rẹ niluu Ikorodu l'Ọjọru.

Alhaji Adio ni, lati kekere loun ti n gbọ awo orin ti Barrister ti kọ wéré, ko to maa kọ orin Fuji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, o ni ti ẹnikan ba sọ pe Barrister kọ lo da Fuji silẹ, o ni ko si ija nibẹ nitori ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran.

Atawẹwẹ tun fikun ọrọ rẹ pe, iṣẹ Fuji lo yọ oun ninu iṣẹ alabaru lọja Ketu ati Mile 12.

O ni oun tun ṣiṣẹ apero sọkọ ati iṣẹ akọle, birikila ṣugbọn iṣẹ Fuji lo yọ ọpọ eeyan to n kọ Fuji loko ẹru.

O tun salaye pe, apọnle ti wọn ba n fun Fela lo yẹ ki wọn maa fun Barrister kaakiri gbogbo agbaye.

Image copyright Facebook/Atawewe

Atawẹwẹ fikun ọrọ rẹ pe, o yẹ ki gbogbo olorin Fuji mọ ere Ayinde Barrister ati ti Alhaji Ayinla Kollington, lati fi gboṣuba fun wọn.

O ni awọn mejeeji ni wọn yọ ọpọ olorin Fuji loko ẹru lonii.

Atawẹwẹ sọ pe, ati ọmọ ọdun mẹrin ni oun ti n kọrin, orin kikọ si lo gbawe kika lọwọ oun.

O ni JSS 3 loun wa nile iwe girama ki oun to kuro nile iwe, amọ o sọ pe oun o kaba