Kidnapping: Aago méje alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun làwọn agbégbọn dí ọ̀nà márosẹ̀ Ibadan

Márosẹ̀ Ibadan sí Eko Image copyright @renoomokri

Kaka ki ewe agbọn dẹ nidi eto aaboorilẹede naijiria to mẹhẹ, n se lo tun n le koko sii.

Idi ni pe oju ọna Ibadan silu Eko ti ọkan balẹ le lori tẹlẹ, ni ipaya tun ti n waye lori rẹ bayii nitori awọn gende agbebọn ti wọn se ọsẹ nla ni irọlẹ ọjọ Isẹgun.

Gẹgẹ bi iroyin naa se wi, agbegbe Ajebọ lopopona Ibadan silu Eko ni isẹlẹ naa ti waye ni deede aago meje alẹ.

Awọn gende agbebọn ti wọn to mẹẹdogun, lo da ọkọ kan duro ti wọn si ji eeyan mẹta gbe loju ibọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkọ ti wọn da duro naa, Toyota Sienna, to jẹ tile iwosan kan nilu Ibadan si lawọn agbegbọn naa gbe silk lai gbe lọ, tawọn ọlọpa si ti ri nibi ti wọn gbe si, bẹẹ ni wọn ti wa lọ si agọ ọlọpa to wa ni abule Ogunmakin nipinlẹ Ogun.

Nigba to n ba akọroyin sọrọ, ọga agba ile iwosan Lafia to wa ladugbo Apata nilu Ibadan, Dokita Ọladipupọ Sule salaye pe, ọmọ oun Kayọde ati osisẹ meji nile iwosan naa ni wọn fori sọta isẹlẹ ijinigbe naa, to si pe orukọ awọn eeyan meji yoku ni Ọpẹyẹmi Abifarin ati Dele Adigun.

Lori iṣẹlẹ naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi sọ fun BBC Yoruba pe kọmisana ọlọpaa ipinlẹ naa, Bashir Makama ti ko awọn oṣiṣẹ alaabo lọ si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lati doola awọn ti wọn jigbe ọhun.

Oyeyẹmi fikun ọrọ rẹ pe awọn eniyan meji miran to farapa lasiko iṣẹlẹ ijinigbe naa ti n gba itọju nileewosan.

Image copyright @NigerianPolice

Ẹwẹ, Dokita Sule ni ọkan oun gbọgbẹ, ti inu oun si bajẹ gidigidi lori isẹlẹ naa nitori oogun lawọn eeyan mẹtẹẹta ti wọn ji gbe naa lọ ra fun ile iwosan naa nilu Eko, asiko ti wọn si n pada bọ lọwọ alẹ ni wọn ko sọwọ awọn ajinigbe.

Dokita Sule fikun pe " Awakọ mọto naa salaye pe, ọkan ninu awọn agbebọn naa sọrọ ni ede oyinbo, nigba tawọn yoku sọrọ ni ede Hausa ati Fulani, wọn ko si ti pe wa lati sọ iru eeyan ti wọn jẹ ati erongba wọn."