Iléeṣẹ́ ológun: Àbájáde ìwádìí wa lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò hàn síta láìpẹ́

Awọn ọmọ ogun Image copyright Getty Images

Ileeṣẹ ologun Naijiria ti bẹrẹ iwadii aṣiri kan to tu pe, awọn ọmọ ogun kan salọ pẹlu owo naira to le ni miliọnu kan ati aabọ Dọla ($1.6).

Bi awọn ọmọ ogun naa, ti wọn jẹ ẹṣọ to n tẹle ọkọ agboworin, ṣe ri aaye gbe owo naa salọ, ko sẹni to mọ.

Amọ ẹnikan nileesẹ ologun fidi rẹ mulẹ fun BBC pe, owo nla kan ti sadeede poora, ati wi pe, wọn ti fi iṣede se ọgagun kan mọle rẹ, ko gbọdọ fi ile rẹ silẹ nilu Abuja.

Osisẹ ologun kan, Onyema Nwachukwu, to ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Iṣẹgun ni olu ileeṣẹ ologun fidi rẹ mulẹ pe iwadii nlọ lọwọ , pẹlu afikun pe, "abajade iwadii naa yoo di mimọ fun araalu ti asiko ba to."

Awọn ipẹẹrẹ ọmọ ologun maarun la gbọ pe wọn ji owo naa gbe.

Bi iroyin kan sọ pe, owo naa to yẹ ki wọn fi gbọ bukata ileeṣẹ ologun ni, ni omiran sọ pe ,ọga ologun kan nigbakan ri lo ni owo naa.

Iroyin sọ pe, awọn ọmọ ogun naa tẹle ọkọ agboworin kan to gbe owo naa lati ilu Sokoto si Kaduna, lati pese aabo fun.

Asiko ti wọn si n lọ lọna ni wọn ja ọkọ gba, wọn bọ aṣọ ọmọ ogun kuro lọrun un wọn, wọn si salọ.

Owo kekere kọ ni ijọba maa n ya sọtọ fun ileeṣẹ eto aabo ninu owo iṣuna lọdọọdun, ṣugbọn awọn ọmọ ogun to wa ni oju ija, paapa, awọn to n doju kọ ikọ Boko Haram, maa n fi gbogbo igba pariwo pe, awọn ko ni irinṣẹ, awọn ko si ri owo ajẹmọnu gba.