Google Map: Ànfààní wo ló wà nínú lílo ẹ̀rọ̀ ajuwe ọnà pẹ̀l'óhùn Nàìjíríà?

Ami idanimọ Google Image copyright TWITTER@GOOGLEAFRICA

Ohun yẹn niyen! Ile iṣẹ Google ti bẹrẹ si ni lo ohun Naijiria lati juwe ọna lawọn opopona ilẹ naa.

Ikede yii jẹyo gẹgẹ bi ile iṣẹ naa ṣe fi awọn ilu mẹrin miran kun eleyi to ti wa nilẹ nibi ti awọn eeyan yoo ti ma lo ẹrọ ajuwe ọna.

Saaju asiko yii, ohun oyinbo lo ma n juwe ọna fawọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ naa ti a si maa mu inira ba awọn ti ko ba gbo ohun ti oyinbo n sọ.

Ramesh Nagarajan to jẹ oludari ọja tita nileeṣẹ naa sọ fun BBC pe ohun Naijiria tawọn fi si inu ẹrọ ajuweọna naa ko yatọ si ti ọmọ Naijiria.

O ṣalaye pe ohun yii yoo si ma pe awọn orukọ adugbo lede wọn gangan eyi ti awọn Naijiria yoo gbọ́.

Image copyright TWITTER@GOOGLEAFRICA
Àkọlé àwòrán Ramesh Nagarajan

''Bi eeyan ba fẹ jẹ anfaani lilo ohun Naijiria yii lori ẹrọ, yoo kan lọ yii kuro lede Gẹẹsi si ede Gẹẹsi ti Naijiria ni.

Diẹ lara awọn aworan ibi ayẹyẹ ti Google ti ṣe ifilọlẹ yii ree ladugbo Lekki nilu Eko.

Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Aworan ayẹyẹ Google
Image copyright Google

Lọpọ igba ni ohun oyinbo a maa ṣi orukọ adugbo Naijiria pe ti ẹlomiran ko si ni mọ pato ohun ti o n sọ.

Ninu awọn ilu ti Google pẹka ẹrọ ajuweọna yii de lati ri Abuja, Benin, Enugu ati Ibadan.