Nigeria Diaspora Day: Ìjọba ní láti ronú jinlẹ̀ nípa òun tó n sọ ọmọ Nàìjíríà d'ero ilẹ ókéèré

Aworan ileeṣẹ Naijiria nilẹ okere

Idagbasoke orileede Naijiria kii ṣe iṣẹ ijọba nikan bi kii ṣe ki awa ti a wa nilu okere naa ṣa ipa ti wa.

Diẹ lara ọrọ tawọn ọmọ Naijiria to n gbe loke okun sọ fun BBC ree lori oun to yẹ ki o jọba lọkan awọn eeyan layajọ awọn ọmọ Naijiria to n gbe oke okun.

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu keje ni ijọba apapọ ya sọtọ lati ṣe agbeyẹwo ohun gbogbo to ni ṣe pẹlu awọn ọmọ Naijiria lẹyin odi.

Ni ọjọ yii, wọn a maa ṣe agbeyẹwo ipa ti awọn to wa ni ilẹ okere le ko lati mu idagbasoke ba Naijiria.

Ojo yi bakan naa maa jẹ anfaani lati ṣe ayẹwo awọn ipenija to n ba awọn eeyan Naijiria nile ati lẹyin odi.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile iṣẹ BBC Yoruba, Ọjọgbọn Adetokunbo Akintayo ṣalaye pe kii ṣe pe o wu ọpọ awọn eeyan lati file silẹ bi kii ṣe pe nnkan ko rọgbọ.

Àkọlé àwòrán,

Ni ọjọ yii, wọn a maa ṣe agbeyẹwo ipa ti awọn to wa ni ilẹ okere le ko lati mu idagbasoke ba Naijiria.

Adetokunbo to ti ṣisẹ oniroyin ni Naijiria fọdun pipẹ ki o to di ero ilẹ Gẹẹsi ni afiwe ko si laarin bi awọn eeyan ilẹ okere ṣe n dari ilu pẹlu ti Naijiria.

''Ijọba ni lati ronu jinlẹ lati koju awọn ipenija to n mu ki awọn ọmọ Naijiria maa sa kuro nilu. Kini awa ọmọ Naijiria fun ara wa le ṣe? Awọn nkan to yẹ ki a ma bere ree lọjọ oni''

O ṣalaye pe nipa eto abo ati ilera, ijọba Naijiria ni lati ṣe ju bi wọn ti n ṣe lọ ki ilu baa le rọgbọ fara ilu.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe nilẹ Gẹẹsi ko si awọn ipenija ti awọn ara ilẹ Naijiria n koju bii ti ijinigbe tabi aisi eto ilera to peye.

Omi pọ ju ọka lọ ṣugbọn...

Arabirin Halima Babamale to jẹ olukọ ni fasiti ilu Ilorin to n tẹsiwaju pẹlu ẹkọ rẹ nilu Malaysia naa sọ iriri tirẹ nipa gbigbe ilu okere.

''Ko si wahala kankan to jọ mọ iru eleyi ti a n koju ni Naijiria nipa aabo ni ilu ti mo wa. Igba to ba wuwa la n rin jade ti awọn oṣiṣẹ alaabo naa si wa ni ṣẹpẹ''

Mo le ni eto wọn nilu yi muna doko daada ti o si wu mi ki ijọba Naijiria naa wo awokọṣe lara wọn.

Àkọlé àwòrán,

Awọn ijọba ilu ta wa ṣe gbogbo eto bo ti ṣe tọ ati bo ti ṣe yẹ

O ni ti awọn to n ṣe ijọba a maa saba rin irinajo lọ si ilu okere ti wọn si ma n ri bi nnkan ti ṣe ri nibẹ.

''O yẹ ki wọn ṣe atunṣe lawọn ibi ti o ba ku diẹ kaato amọ ara ilu naa nipa ti awọn naa le ko.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ẹtàn ni àwọn ọ̀rẹ́ fi ń tan èèyàn lọ si Libya pé iṣẹ́ gidi wà níbẹ̀

Àkọlé fídíò,

Abikẹ Dabiri: Iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ Naptin àti àwọn aṣọ́bodè Nàìjíríà