'Jollof, Iyan, Asaro, Ewa Alagbado kìí wọ́n n'ílé oúnjẹ wá ní Egypt'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Cairo: Ilé oúnjẹ fáwọn Yorùbá ní Cairo, Egypt

Lẹ́yin ti ikọ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ṣe aṣeyọri ti wọn gba lara awọn ami ẹyẹ bọ wale lati idije AFCON 2019 to waye lorilẹede Egypt, awọn nkan apawo wọle mii ṣi wa tawọn ọmọ Naijiria ń gbe ṣe lorilẹede naa.

Ile ounjẹ Yoruba yii jẹ ọkan lara iṣẹ ọwọ awọn ọmọ Naijiria to n gbe ni ilu Egypt.

Ko jọ bi ẹni pe kata kara ounjẹ tiwa n tiwa Yoruba lọhun nira fun wọn pẹlu ifọrọwanilẹnuwo akọroyin BBC Yoruba.

Koda wọọ wọọ lero maa n wọ lati wa jẹ ounjẹ Yoruba ni kete ti wọn ba ti ṣilẹkun titi di aago mejila oru.

Ṣugbọn bawo ni wọn ṣe ń ra iru, ewedu, ẹfọ Gure, Tẹtẹ ṣe ń rọrùn fun wọn bi wọn ṣe sọ?

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii