Child Education: Mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún ọmọdé ni kò sí níléèwé lórílẹ̀èdè Nàìjíríà

Awọn ọmọde kan Image copyright Getty Images

Ninu igba miliọnu awọn eeyan to n gbe lorilẹede Naijiria loni, njẹ o mọ pe miliọnu mẹrindinlogun awọn ewe ni ko ri ileewe lọ bayii?

Ọrọ yii kii ṣe wọn ni-wọn pe o! Minisita feto ẹkọ ni saa iṣejọba akọkọ aarẹ Muhammadu Buhari, Adamu Adamu lo kede iroyin yii. Ṣe ẹ si mọ pe ọrọ ti akuwarapa ba sọ latode ọrun ni, eyi lo si n mu ki ọpọ maa kaya soke lori ọrọ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKí ló máa ń wú ìyá Nike Davies lori láti wé gèlè ràbàtá?

Niwaju awọn aṣoju orilẹede Naijiria ni Adamu Adamu ti ṣi aṣọ loju ọrọ naa.

Eyi wa tako nọmba ti awọn eeyan kan n gbe kaakiri tẹlẹ pe miliọnu mẹtala lawọn majeṣin ti ko si ni ileewe lọwọ bayii.

Adamu, to jẹ ọkan lara awọn ti orukọ wọn ṣẹṣẹ jade niwaju ile aṣofin agba gẹgẹ bii minisita ni saa keji Aarẹ Buhari ṣalaye pe ẹri maa jẹ mi niṣo lori ọrọ yii wa ninu eto onka tuntun ti wọn ṣe loṣu keji ọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDele Momodu : Lẹ́yìn Buhari àti Atiku, èrò ọjà làwọn olùdíje yóòkù ní ìdìbò 2019

Nigba ti yoo tun pari ọrọ, Adamu ni miliọnu mẹwa ninu awọn majeṣin yii lo yẹ ko wa nileewe alakọbẹrẹ ṣugbọn ti wọn ko si nibẹ bayii. Miliọnu mẹfa ninu wọn ni ọkọ iwe wọn taku ni kete ti wọn pari iwe alakọbẹrẹ. Eyi tumọ si pe wọn ko lanfani ati lọ sileewe girama bayii.

Ṣe awọn agba bọ wọn ni ajala ta n naa ọ, ẹyin naa kọhun. Adamu ni ọda owo awo olokun lo n fa wahala yii o. O ni aifi owo to jọju sẹka eto ẹkọ latọdọ ijọba apapọ atawọn ijọba ipinlẹ lo fa eyi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...

Bakan naa lo tun fa bẹmbẹ ọrọ ya o nigba to wi pe awọn eeyan to n jẹ ajẹbanu lorilẹede Naijiria tun fẹ ṣe bi ẹni n pọ sii lọwọ yii pẹlupẹlu ipolongo igbogun tiwa ijẹkujẹ ti Aarẹ Buhari n lọgun rẹ tan-tan-tan.

Amọṣa, aarẹ ile aṣofin agba ti sọ pe awọn yoo mu gẹgẹ bi iṣẹ lati rii pe awọn ọmọ wọnyii pada sileewe lẹyẹ-o-ṣọka.