Ààrẹ Beji Caid Essebsi, torílẹ̀èdè Tunisia jáde fáyé

AarẹBeji Caid Essebsi Image copyright AFP

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé Aarẹ akọkọ ti wọn kọkọ finu findọ yan ni orilẹede Tunisia, Beji Caid Essebsi ti jade laye lẹni ọdun mejilelaadọrun.

Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Tunisia lo kede rẹ.

Oun ni aarẹ to dagba julọ lagbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Jollof, Iyan, Asaro, Ewa Alagbado kìí wọ́n n'ílé oúnjẹ wá ní Egypt'

Wọn gbee lọ sileewosan ni ọjọru bi o tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ilẹ naa ko sọ idi to fi lọ gba itọju nileewosan.

Ni ọdun 2014 ni ọgbẹni Essebsi bori ninu idibo apapọ ti awọn orilẹede naa ṣe lọdun 2014 lẹyin wahala awọn larubawa lagbegbe naa.

Ṣaaju ni ọdun yii, o kede pe oun ko ni dije fun ibo mọ lasiko idibo orilẹede naa ti wọn n fojusọna nigba naa pe yoo waye loṣu kọkanla ọdun yii.

Iroyin sọ pe wọn gbe aarẹ Essbsi lọ sileewosan ni oṣu to kọja nitori ohun ti awọn alaṣẹ orilẹede naa kan pe ni 'wahala ilera to lagbara gidigidi'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYoruba Culture: àṣà ìkínni ṣe pàtàkì nílẹ̀ Oodua

Nigba naa, olotu ijọba orilẹede ọhun, Youssef Chahed to bẹẹ wo nileewosan rọ awọn eeyan lati yẹra fun iroyin irọ nipa ipo ilera rẹ nigba naa.

Wọn yọ Aarẹ Tunisia nigba kan ri, Zine el-Abedine Ben Ali ni ọdun 2011 lẹyin to lo ọdun mẹtalelogun ni ipo.

Lati igba yii wa ni orilẹede Tunisia ti gba oriyin gẹgẹ bi orilẹede kan ṣoṣo lagbaye to gba eto iṣejọba tiwantiwa labẹ abajade iwọde ẹhonu araalu eyi ti wọn pe ni arab spring.

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii

Related Topics