EFCC kó akẹ́kọ̀ọ́ fásitì UNIOSUN làwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bá fọ́n sígboro

efcc

Awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ti ko awọn akẹkọ ileewe fasiti ipinlẹ Ọṣun University of Osun State lori ẹsun pe wọn n ṣe owo gbajuẹ ati Yahoyahoo.

Iroyin ti o n tẹ wa lọwọ ṣalaye pe ni owurọ Ọjọbọ ni awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC naa ya bo ileegbe awọn akẹkọ fasiti kan to wa lagbegbe Oke Baalẹ ni ilu Osogbo ti wọn si ko awọn akẹkọ kan nibẹ.

Agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Tony Orilade, fi idi iroyin naa mulẹ fun BBC News Yoruba. O ni awọn oṣiṣẹ ajọ naa lo ṣe iṣẹ naa ṣugbọn ko tii le fi idi rẹ mulẹ iye awọn ti wọn mu nibẹ.

Amọṣa, alukoro ileewe fasiti UNIOSUN, Ọgbẹni Adeyẹmi pẹlu ṣalaye fun BBC pe awọn alaṣẹ ileewe naa ti n gbe igbesẹ lori rẹ.

Àkọlé fídíò,

Dele Momodu : Lẹ́yìn Buhari àti Atiku, èrò ọjà làwọn olùdíje yóòkù ní ìdìbò 2019

O ni lara awọn ileegbe aladani to wa fawọn akẹkọ ileewe naa ni o ti ṣẹlẹ.

Bakan naa lo ṣalaye pe iroyin ti awọn akẹkọ naa n fi to oun leti ni pe nnkan bi akẹkọ ọgbọn si marundinlogoji ni awọn oṣiṣẹ EFCC naa ko nibẹ.

Ọrọ ọhun fẹrẹẹ da omi alaafia ilu ru nilu Oṣogbo lọjọbọ pẹlu bi awọn akẹkọ ileewe naa ṣe fọn ka si igboro lati fi ẹhonu han lori awọn akẹgbẹ wọn ti wọn mu naa.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, ni a gbọ pe o ṣẹṣẹ wa pẹtu si ọkan awọn akẹkọ naa ki wọn to bu omi suuru mu.

Àkọlé fídíò,

Yinka Ayefele: Oṣù àwọn ìbẹ́ta mi kò pé ní kò jẹ́ kí n kọ́kọ́ kéde ìbí wọn