Ondo Assembly: Ejò da ìjókòó ilé rú , l'àwọn aṣòfin bá fẹsẹ̀ fẹ

Ejo

Ọrọ di bo o lọ, ya a mi nigba ti ejo afayafa deede jabọ pi lati ori aja sinu ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo lasiko ti ijoko ile n lọ lọwọ.

Iroyin sọ pe l'Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti ijiroro nlọ lọwọ , eyi to mu ki onikaluku awọn aṣofin ọhun o sa asala fun ẹmi wọn.

Sisa ti wọn sa yii fi opin si ijoko ati ijiroro to n lọ lọwọ.

Àkọlé fídíò,

Ejo abami to n mu owo ni ajọ Jambu

Amọ ṣa, ejo naa raaye salọ.

Awọn aṣofin si ti sọ ipade ijiroro wọn di ọjọ miran, ọjọ ire titi ti atunṣe yoo fi de ba gbọngan ile aṣofin.