Action Against Hunger: Àwọn òṣìṣẹ́ olùrànlọ́wọ́ képe ìjọba kó gbàwọn lọ́wọ́ ajínigbé

Òṣìṣẹ olùrànlọ́wọ́ mẹ́fà ń bẹ̀bẹ̀ f'ómìnira lọ́wọ́ ajínigbé Image copyright AFP

Ijọba orilẹede Naijiria ti bẹrẹ ijiroro pẹlu awọn to ji awọn oṣiṣẹ mẹfa to jẹ ti ajọ alaanu kan gbe lapa ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Fidio kan lo ṣafihan awọn oṣiṣẹ naa to jẹ ti ajọ to n gbogbu ti ebi, Action Against Hunger, nibi ti wọn ti n bẹbẹ fun ominira lọwọ awọn agbesumọnmi to ji wọn gbe.

Obinrin kan to wa lara wọn sọ pe wọn fiya jẹ awọn ki wọn to gbe awọn lọ si ibi tawọn ko mọ rara.

Ṣugbọn oludamọran lori ọrọ iroyin si Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu to ba BBC sọrọ fidi rẹ mu lẹ pe ijọba ti bẹrẹ si ni ba awọn ajinigbe naa sọrọ lori bi wọn yoo ṣe dawọn silẹ.

Shehu ni oun nigbagbọ pe awọn oṣiṣẹ mẹfa naa yoo gba ominira laipẹ lọwọ awọn ajinigbe.

Ajọ oluranlọwọ Action Against Hunger, ṣalaye pe awọn da awọn oṣiṣẹ oluranlọwọ mẹfa to wa ninu fidio naa mọ.

Ọkan lara wọn ti orukọ rẹ n jẹ, Grace da iborun alawọ buluu bori, bẹẹ lawọn ọkunrin marun un joko lẹgbẹ rẹ.

Obinrin naa ke gbajare si ijọba Naijiria ati ijọba agbaye lati gbawọn lọwọ awọn ajinigbe ni kiakia.

Ni ibẹrẹ osẹ yii ni ajọ oluranlọwọ naa fi atẹjade kan sita pe awọn eeyan kan kọlu awọn oṣiṣẹ wọn to n rinrin ajo lọ si ilu Damasak, nipinlẹ Borno.

Wọn tun sọ ninu atẹjade naa pe awakọ kan ku ninu ikọlu ọhun, bakan naa ni wọn ko ri awọn ti wọn n jọ n rinrin ajo.

Ẹwẹ, awọn ologun sọ pe awọn ti gbiyanju agbara lati fopin si awọn agbesumọmi ati ijinigbe ṣugbọn egberin ọtẹ lọrọ ọhun.