Kayeefi: Facebook ni Woli Arole Jesu fi tàn an wá ìjọ, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Igboora: Wòlíì ni mí, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀gá tó kọ́ mi níṣẹ́ òògùn owó ní kí n má dárúkọ

Hmmmmn... Ni ilu Igboora, ijọ kan n bẹ nibẹ...

Ṣébi wọn ni ibi gbogbo là ń dáná alẹ́ nitori naa, Kayefi ti oṣu yii kii ṣe lati tabuku ba ẹnikẹni, ẹgbẹ tabi ijọ kankan.

Ṣugbọn ijọ yii ti wọn darukọ rẹ ninu fidio to wa loke wa ni ilu Igboora, wọn si ni Woli kan to n dari wọn.

Wolii Aroye Jesu kọ ni oludasilẹ ijọ o ṣugbọn nigba ti oludasil ijọ papoda, wọn lọ ba baba kan niluu.

Baba ọhun lo mu ẹni kan ti o pe ni Wolii wa lati maa wa dari wọn ninu ijọ.

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ ti ko ni ṣee kọ jade tabi ka tan, lẹnu kan de, ẹ wo fọnran yii lati wo gboogbo alaye bi Bosede Oguntunde lati ilu Ilorin, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta koda to ti ni ọmọ-ọmọ ṣe di ẹni ti n pọ owó fún Woli Aroye Jesu ni ilu Igboora.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii