Ìtàn Mánigbàgbé: Kí ni ẹ rántí nípa Israel Adebajo, gbajúmọ́ oníṣòwò tó dá 'Stationery Stores' sílẹ̀?

Aworan Israel Adebajo Image copyright Prof. Adekeye Adebajo
Àkọlé àwòrán Gbajumọ to gbalafẹ ni Israel Adebajo

Bi a ba ka awọn gbajumọ ni meni meji lasiko ti o logba, yoo ṣoro ki a ma mẹnu ba ilumọọka oniṣowo ọmọ bibi ilu Ẹpẹ nni, Israel Adebayo Ogunyeade Adebajo.

Ninu awọn gbajumọ to gbalafẹ nilu Eko lasiko aye rẹ, ko fẹrẹẹ si ẹlẹgbẹ Israel Adebajo.

Lẹka karakata ati owo ṣiṣe, Israel Adebajọ lalẹ gaara, ti orukọ ile iṣẹ itawe rẹ Stationery Stores si kale ka'ko.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kinni, ọdun 1920 ni wọn bi i ni Imobi, Epe, nilu Eko.

Nigba ti yoo fi faye silẹ lẹni ọmọ ọdun mọkandinlaadọta, orukọ Adebajo ti tan kaakiri ti o si ti lapa lagbo ere bọọlu nitori bi o ti ṣe dari ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Stationery Stores.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Flaming Flamingos

Awọn to ba n fi ọkan tẹle ere boolu nilu Eko ati kaakiri orile-ede Naijiria lasiko igba ti ọlaju Premiership ko ti gbode, kete ti a ba darukọ Stationery Stores ni wọn yoo ranti ẹgbẹ agbabọọlu ti o milẹ titi yii.

Ẹyẹ meji kii jẹ aṣa, ti ẹ ba ti n gbọ 'Up Stores!' 'Up Super' ''Triple Flaming''ati ''Gbogbo wa lọrẹ Adebajo'' Stationery Stores lawọn eeyan n kan sara si.

Lasiko ta n wi yii, Stationery Stores ti orukọ ipilẹ rẹ jẹ Adebajo Babes jẹ ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria akọkọ ti yoo kopa ninu idije African Champions Cup ti a mọ si CAF Champions League lonii.

Image copyright Adewemimo A. Adebajo
Àkọlé àwòrán Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kinni, ọdun 1920 ni wọn bi i ni Imobi, Epe, nilu Eko.

Adebajo na owo, o na ara lati rii pe ẹgbẹ yi tàn bi oṣumare ti pupọ awọn alatilẹyin rẹ si kan sara si ọgbọn ati oye ti o fi ṣakoso ẹgbẹ naa.

1958 lo ra ẹgbẹ agbabọọlu ti orukọ rẹ n jẹ Oluwole Philips Football Club ti o si yi orukọ rẹ pada si Stationery Stores Football Club.

Owo to n wọle lati awọn ile itawe rẹ, Stationery Stores ti o da silẹ nilu Eko, Ibadan, Enugu ati Port Harcourt ni Adebajo fi n tukọ ẹgbẹ naa.

Ni igba ti a n sọrọ rẹ yii, awọn ile iṣẹ nla bi Leventis, UAC, Nigerian Railway Corporation, ati Electricity Corporation of Nigeria (ECN) ni wọn ni ikimi lati da ẹgbẹ agbabọọlu silẹ ni orukọ wọn.

Image copyright Adégbóyèga Adébàjò
Àkọlé àwòrán Awọn agbabọọlu ẹgbẹ Stationery Stores wa kẹdun iku oludasilẹ ẹgbẹ wọn nigba to ku

Bi awọn eeyan ṣe n gbadun ere bọọlu lati ẹsẹ awọn agbabọọlu Stationery Stores ni owo n ya wọle fun ile iṣẹ ti o n ba a jẹ orukọ.

Ipolowo ọja nla ni ibaṣepo ẹgbẹ agbabọọlu naa jẹ fun ile iṣẹ Adebajo ti eleyi si mu ki okiki rẹ ati owo rẹ maa pọ sii.

Ẹgbẹ Stationery Stores jẹ ẹgbẹ tawọn ololufẹ ere bọọlu nifẹ si pupọ ti pupọ ninu awọn agbabọọlu naa si kopa ninu idije fun ikọ agbabọọlu Naijiria Green Eagles nigba naa.

Lọdun 1968 ti Naijiria kopa ninu idije Olympics, mẹsan an ninu awọn agbabọọlu to ṣoju Naijiria ni Mexico jẹ agbabọọlu lati ẹgbẹ Stationery Stores.

Image copyright Adégbóyèga Adébàjò
Àkọlé àwòrán Adebajo ati awọn ọmọ rẹ nibi apeje ajọyọ ife ẹyẹ Challenge Cup lọdun 1968.

Nigba kigba ti Stationery Stores ba fẹ koju awọn akẹgbẹ wọn, awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa yoo gba ọkọ lati Ibadan wa si Eko tori pe wọn fẹ wo ifẹsẹwọnsẹ wọn.

Labẹ akoso Adebajo, Stationery Stores ni awọn ilumọọka agbabọọlu bi Haruna 'Master Dribbler' Ilerika, Yomi Peters, Julius Akpele, Peter Rufai, Ike Shorounmu, Yakubu Mambo ati Mudashiru Lawal.

Wọn gba Lagos State Challenge Cup ni 1974 ati 1976; FA Cup ni 1982 ati 1990; Ife ẹyẹ Liigi ni 1992; ti wọn si kuna lati gba ife ẹyẹ African Cup Winners' Cup lọdun 1981 lẹyin ti wọn fidi rẹmi lọwọ Union Douala Cameroon.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan

Awọn olorin bii King Sunny Ade naa gboṣuba kare fun Stationery Stores ninu awo orin oriṣiriṣi ti wọn gbe jade lasiko naa.

Gbogbo aṣeyọri Stationery Stores wọnyii ko ṣẹyin Israel Adebajo.

Image copyright Adégbóyèga Adébàjò
Àkọlé àwòrán Gbogbo awọn agbabọọlu Stationery Stores lo jijọ gbe psoi Adebajo

Ẹwẹ, Stationery Stores gba ife ẹyẹ Challenge Cup lẹẹmeeji lera lọdun 1967 ati 1968 ti iku Adebajo si di ọna gbigba ife naa ni igba ẹkẹẹta lọdun 1969.

Ọjọ kẹẹdọgbọn, osu keje, ọdun 1969 ni Israel Adebajo dagbere faye!

Wọn sin oku rẹ si Odo-Naforija ni Epe, ilu Eko.

Lẹyin iku rẹ, pupọ awọn agbabọọlu ẹgbẹ Stationery Stores to jẹ ọmọ ilẹ Ghana pada sile ti awọn miran si lọ gba fun ẹgbẹ ECN ati Ngeria Airways.

Adebajo fi ọpọ ọmọ ati iyawo silẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌsẹ́yìn: Ilé aṣọ òkè alárà ǹ barà