Power: Ṣé ẹ̀mí ilé aṣòfin lè gbé ṣíṣe ìwádìí 16 bílíọ̀nù owó àgbàṣe iná ọba Nàìjíríà?

Aworan opo ina

Foniku fọla dide to n ba ẹka ina ọba lorile-ede Naijiria jẹ ọrọ kan to n kọ ara ilu ati ijọba lominu.

Ọrọ naa lagbara de bi pe awọn onwoye ni kete ti wọn ba ti ribi wa wọrọkọ fi ṣada lẹka yii ti ijọba si sọ ji pada, ohun gbogbo yoo bọ sipo pada.

Lati le e wa ojutu si ọrọ naa, awọn aṣojuṣofin ti wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ lorile-ede Naijiria ti pinnu lati tọ pinpin bi ijọba to ti kọja laarin ọdun 1999 si 2007 ṣe na biliọnu mẹrindinlogun dọla.

Bẹẹ wọn ni wọn ko mu iyipada kankan ba ẹka ina ọba.

Lọjọbọ ni ile ṣe ipinnu yii ti wọn si ni awọn yoo tọ pinpin ijọba to kọja bẹrẹ lati ori aarẹ Olusegun Obasanjo, Umaru Musa Yar Adua, Goodluck Jonathan to fi mọ ti Muhammadu Buhari to wa lori oye bayi.

Igbesẹ yi jẹ eleyi ti awọn eeyan ti n kan sara si ṣugbọn ibeere to gba ẹnu ara ilu bayi ni pe ṣe ẹmi ile aṣofin le gbe ṣise iwaadi to peye lati le mọ wulẹwulẹ ọrọ yi?

Atari ajanaku lọrọ to wa nilẹ yi

Lati ọdun 2009 ni ọrọ iwadi owo agbaṣe lẹka yi ti n mẹhẹ.

Ni igba naa lọhun,awọn ọmọ ile fọwọ rọ iwaadi ti igbimọ ile lori ina ọba gbe jade ti wọn si tẹnbẹlu abajade iwaadi naa.

Lara ohun ti iwaadi naa daba ni pe ki ajọ to n ṣe iwadi iwa jẹ́gudujẹra ṣe iwadi aarẹ Olusegun Obasanjo ati Gomina ana ipinlẹ Ondo Olusegun Agagu lori ọrọ naa.

Àkọlé àwòrán,

Lati ọdun 2009 ni ọrọ iwadi owo agbaṣe lẹka yi ti n mẹhẹ.

Koda igbimọ naa daba pe ki wọn ṣe iwadi Gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ ri,Senatọ Liyel Imoke ati Minisita fọrọ ohun amuṣagbara Alhaji Abdulhamid Ahmed.

Amọ ko si ohun to tẹyin iwadi naa bọ to loju tu.

Ile iṣẹ BBC gbiyanju lati ba Dimeji Bankole to jẹ olori ile nigba naa sọrọ lori igbesẹ tuntun yi amọ o ni ohun kolọrọ sọ nipa rẹ aya fi ti ile ba pari iwadi ti wọ́n lawọn fẹ ṣe yi

Bi ẹ ba ṣe iwadii, ẹ ri pe ẹ se de oju ami-SERAP

Imọran re e lati ọdọ adari ajọ SERAP, Adetokunbo Mumini fawọn aṣojuṣofin Naijiria ti wọn lawọn fẹ se iwadi owo ti ijọba ti na lori ẹka ina ọba.

Mumini sọrọ yi ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba.

Àkọlé àwòrán,

Amọ ko si ohun to tẹyin iwadii naa bọ to loju tu.

O ni Naijiria o ṣẹsẹ ma ṣe iwadii lori ọrọ yi,tori naa ki wọn ma wulẹ dawọ le iwadii ti wọn o ni tele abajade rẹ.

Mumini ni o ṣeni laanu pe Naijiria ko ti ri ọrọ yanju nipa ẹka yi ati pe bi eeyan ba ṣẹṣẹ n ronu ati ṣe iwadii dipo ko ma mu ọrọ abayọ wa,apẹrẹ pe ko ni nnkan ṣe ni.