Ooni Ife ké sí olóòtú ìjọba Gẹ̀ẹ́sì tuntun pé kó má gbàgbé ìlérí tó ṣe fún gbogbo àgbáyé

Ooni Ife, aṣoju ijọba ilẹ Gẹẹsi pẹlu Olori rẹ, Yeyelua Naomi Ogunwusi

Ọọni ile ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ti fi ohun ranṣẹ si olootu ijọba tuntun lorilẹede Gẹẹsi, Boris Johnson pe ko ma ṣe gbagbe ileri to ṣe ninu ọrọ akọsọ rẹ gẹgẹ bii olootu ni ọjọru ninu eyi to ti ni ọwọ araalu ni agbara iṣejọba wa.

Àkọlé fídíò,

Kayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó

Ọọni Ogunwusi ni bi Boris Johnson ba joun gbe, ko maa johun gbe o nitori gbogbo agbaye lo n reti ipa rere ti o nii ko ninu idagbasoke ọmọniyan.

Ọọni ile Ifẹ sọ eyi lasiko to gbalejo aṣoju ijọba ilẹ Gẹẹsi, Catriona Laing, ni aafin rẹ, Ile Oodua nilu ile Ifẹ.

O ni adura oun fun olootu ijọba tuntun naa lorukọ awọn alalẹ ilẹ Yoruba ni pe yoo ṣe rere ni ipo rẹ tuntun naa.

Àkọlé fídíò,

LASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...

Mo nifẹ si ọrọ akọkọ ti olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi sọ ninu eyi to ti wi pe ọwọ araalu lagbara wa. Mo si fi anfani yii rọ oun ati ikọ iṣejọba rẹ lati ṣiṣẹ takuntakun ki wọn lee mu ileri ti wọn ṣe fun gbogbo agbaye ṣẹ."

Bakan naa lo tun kan sara si aṣoju ijọba ilẹ Gẹẹsi lorilẹede Naijiria, Arabinrin Catriona Laing fun ilakaka rẹ lati rii pe ajọṣepọ to dan mọran wa laarin orilẹede Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi.

Ọọniriṣa, Adeyẹye Ogunwusi ko da gbalejo aṣoju ijọba ilẹ Gẹẹsi naa, oun pẹlu Olori rẹ, Yeyelua Naomi Ogunwusi atawọn agbagba Ile Ifẹ ni wọn ki arabinrin Catriona Laing kaabọ si ile Oodua nileefẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Pope Francis appealed for peace after performing the rare gesture