Oluwo ti Iwo: O yẹ́ ká rán àwọn Fulani lọ ìlú òyìnbó láti kẹ́kọ̀ọ́

Oluwo ti Iwo
Àkọlé àwòrán,

Oluwo ti Iwo

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti ni wahala to ṣẹ n de ni Naijiria yii, kii ṣe oni lo ti bẹrẹ.

Ọba Abdulrasheed tẹnu bọ owe lati fi bẹrẹ ọrọ o ni, "Ọmọ ta o kọ lo n gbe'le ta a kọ ta". O fi eyi s pe awọn ọmọ aye ode ko mọ itan.

"Ẹyin ọmọde isinsinyii, ẹ o mọ itan lẹ fi n lọ sori ẹrọ ayelujara lọ kọ ohun to wu yin nipa ọrọ aabo to da orilẹ-ede Naijiria laamu lọwọlọwọ.

"Awọn Fulani ti wa laarin wa ti pẹ, wọn le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (500,000)".

Oluwo ni ninu itan ilẹ Yoruba, "o ti le ni irinwo ọdun ti Fulani ti n gbe laarin wa".

Oluwo ṣalaye pe inu igbo rere nile Fulani koda, wọn mọ igbo wa ju wa lọ".

Iha ti Ijọba Naijiria kọ si ipenija abo

Àkọlé àwòrán,

Oluwo ṣalaye pe inu igbo rere nile Fulani koda, wọn mọ igbo wa ju wa lọ".

Kabiyesi ba mẹnu ba ohun ti ijọba n sọ nipa ipaniyan lonii, ijinigbe lọla ni Naijiria.

Awọn oloṣelu ko naani eeyan lo fa ohun to n ṣẹlẹ si Naijiria bayii eyi ti ko si tii ṣẹlẹ ri.

O ni gbogbo iṣẹlẹ a n ra ibo lasiko idibo, kii ṣẹlẹ tẹlẹ ni Naijiria, oni bi wọn ba mọ itan ni, itan atijọ lo yẹ ki wọn fi yanju isoro oni.

"Mo rí ogun, mo jagun, emi ni mo le sọ nipa bi asiko ogun ṣe maa n ri. Mo wa ninu ogun Liberia ni 1989".

"Hitler, Latosa, Ogedengbe... ogun kọ ni gbogbo iyẹn, a ni ẹ o mọ asiko ti ẹ o mu abọ lọwọ ti ẹ o si ni ri ounjẹ jẹ".

Ẹ jẹ́ kí n sọ ọgbọ́n tí ẹ lè fi mú Fulani

Ẹ mu àwọn Fulani lọ ilu oyinbo ki wọn lọ kọ bi wọn ṣe n ṣe eto ẹran igbalode

"Apẹrẹ gidi ni mi lori ọrọ Fulani, Ọba temi wa Fulani lọle ninu igbo rere, mo wọ inu Gaa Fulani lọ".

Kabiyesi Akanbi ni ohun ko jọba tori ati kowo jẹ, oun fẹ fara sin ilu ni. Tori eyi, "ọmọ Nàiìjíríà náà ni Fulani, mu wọn bi arakunrin yin".

Oluwo ni "kò sẹ́ni tó lè bá Fulani tàbí ọmọ wọn jà nínú igbó" tori naa ọgbọn laa fi n ṣe gbogbo nkan.

RUGA!

RUGA, Ruga tí wọ́n ń pariwo kò lè tó awọn 500,000 Fulani tó wà nínú igbó".

Ọpọlọpọ eto ti yoo ṣe wọn lanfani bii idanilẹkọọ lo yẹ ki ijọba kọkọ ṣe ki wọn wa fi ofin lelẹ.

Ẹwẹ Kabiyesi ni bí ẹnikẹni bá ti rú òfin, ko si iru ẹya to le jẹ, "ẹ mọ̀ọ́ pa wọ́n, ẹ o ri i kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́".

"Òfin kí wọ́n máa pa ajínigbé ló yẹ kí ìjọba ṣe".

Oluwo ni fun apẹrẹ, "Boo ba kowo jẹ ni China, pipa ni!".

Tori naa "ọmọ Yorùbá tó bá sọ̀rọ̀ ogun, ẹ gbé e!".

"Ẹsan lo n ke lori Naijiria, eeyan tẹẹ pa ti pọ ju ni, ti ẹ fi ro pe Fulani nikan lo n pa eeyan".

Bi bẹẹ kọ, o yẹ ki Naijiria ti di irinwo miliọnu bayii".

Àkọlé fídíò,

Kayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó

Idi ti awọn kan ṣe n sọ pé mo n ṣe akọ:

Eeyan kii jẹ Oluwo, ipo ade, ti mo gba ni wọn n pe ni Oluwo

"Awọn kan tilẹ ni wọn ni Gay ni mi, Yahoo yahoo ni mi..."

"Awọn baba yin wa ninu itan, o si yẹ ki ẹ ju awọn baba yin lọ, iyẹn lemi n ṣe aridaju rẹ laye temi".

"Bóò bá ta Ọba rẹ lọ́pọ̀, òó lè rí i ní gbànjo".

Kabiyesi ni inu maa n bi awọn eniyan pe oun n ṣakọ, o ni "ṣe bi iwọ ba jọba oo ni ṣakọ?"

Ṣe iwọ ti ri Iwo ri lori Google, Facebook, BBC,...

Oluwo ni àwọn òwe Yorùbá kan wà tó yẹ kí a yí padà lédè Yorùbá

  • B'ọ̀mọdé bá láṣọ bí àgbà kò lè lákìísà bí àgbà
  • Erin kìí fọn kí ọmọ rẹ̀ fọn

- ṣé a ò yí ilé koríko padà máá wá kọ́ ilé bíríkì báyìí?

"Ìwọ tóò bá ti fẹ́ yí ǹkan padà, ṣì lọ máa bulù sójú".

"O yẹ ki a jẹ́ ki awọn aṣa wa ba igba mu ko le maa wu awọn eniyan.

Eyi lo n jẹ ki awọn ọmọ wa maa sa fun aṣa. Emi ti n jẹ ki aṣa wa wu awọn eeyan lati ilu Iwo.

Kabiyesi ba tun fi owe pari ọrọ awn to ni oun maa n ṣakọ pe "Olówó máa ń jẹun jẹ́jẹ́ ni, òtòsì nìí yọkùn gàkìa-gàkià"

Imaamu tó ní mo fẹ́ bá ìyàwó òun sùn ti fẹ́ tẹ́:

Oluwo ni ko yẹ kí ààfáà máa sọ̀rọ̀ sí ọba jau jau.

"Imam ọhun ti wa bẹbẹ lọdọ mi lọpọ igba nitori naa igba to ṣe e de ibi gẹgẹ, o ti fẹ tẹ nu un".

"Tọọ ba ti ri ọba fin, o ti padanu gbogbo ohun too ni ati to n ri lọdọ ọba; a o si wa wa ọta rẹ a o gbe gbogbo ohun toun ri gba lọwọ ọba fun ọta rẹ".

Àkọlé àwòrán,

Oluwo ati Olulufẹ rẹ

Kabiyesi fi iyawo rẹ yangan - "Ṣé bóo rí ìyàwó mi bó ṣe dùn, ṣe ìyàwó Ààfàá ló wá ń kàn?".

Kò sí aáwọ̀ láàrin èmi àtàwọn Ọba Yorùbá tó kù, àhesọ ni:

Oluwo ni lori ọrọ ibaṣepọ laarin oun atawọn Ọba alaye to ku nilẹ Yoruba, awọn jọ maa n ṣepade pọ ni.

"Ilu Iwo ló yẹ kó kọ́kọ́ gba Sultan àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà".

Oluwo ni Sultan tumọ si Ọba lede Yoruba. O ni bo ba ṣe orile-ede Germany ni, "Konid Abdurasheed Adewale Akanbi lo yẹ ki n maa jẹ"

Kabiyesi ba ni ko da "Oriṣa ni gbogbo yin" pẹ̀lu alaye lẹnu Oluwo.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii