Kidnapped Turkish Nationals: Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara dóòlà ọmọ Turkey mẹ́rin tí wọ́n jígbé

Awọn ọmọ orilẹede Turkey Image copyright others
Àkọlé àwòrán Alẹ ọjọ Abamẹta to kọja ni wọn ji awọn ọmọ ilẹ okeere naa gbe nile ọti kan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ni oun ti ri awọn ọmọ orilẹ-ede Turkey mẹrin ti awọn ajinigbe gbe pamọ ni ipinlẹ naa gba pada.

Ọgbẹni Kayode Egbetokun sọ fun BBC Yoruba pe ọjọ Ẹti ni awọn ọlọpaa ri wọn doola ninu igbo kanA óò wá àwọn ọmọ ilẹ̀ Turkey mẹ́rin tí wọ́n jígbé rí láàyè- Ọlọ́pàá Kwara.

"Gbogbo awọn ọlọdẹ ibilẹ la jọ ṣiṣẹ naa. Bakan naa ni ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa naa fi awọn kan ranṣẹ si wa lati ilu Abuja."

Ẹgbẹtokun sọ pe Ọjọbọ ni ọwọ ti kọkọ tẹ ọkan lara awọn ajinigbe naa pẹlu ibọn AK-47 lọwọ rẹ, ti ọwọ si tun tẹ awọn meji mi lọjọ Ẹti.

Image copyright others

"Mimu ti a mu awọn meji yii mu so eso rere nitori pe o finna mọ awọn to ku lati le yọnda awọn to wa ni igbekun wọn lai gba owo."

Ṣaaju ni awọn ajinigbe naa sọ pe awọn yoo gba irinwo miliọnu Naira ki wọn o to le tu wọn silẹ. Lẹyin eyi ni wọn tun din ku si ọgọrun un miliọnu Naira.

Amọ ṣa, Egbetokun sọ pe wọn ko san owo kankan fun itusilẹ awọn ọmọ ilẹ okeere naa.

"Nibayii, ati yọnda wọn, wọn si ti wa lọna Abuja lati lọ ba awọn ọga wọn."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDele Momodu : Lẹ́yìn Buhari àti Atiku, èrò ọjà làwọn olùdíje yóòkù ní ìdìbò 2019

Alẹ ọjọ Abamẹta to kọja ni wọn ji awọn ọmọ ilẹ okeere naa to jẹ oṣiṣẹ abanikọle gbe nile ọti kan.

Bakan naa lo ṣalaye kikun lori ipa pataki ti awọn fijilante ko ni Kwara nipa wiwọ inu igbo lọ titi wọn fi ṣawari awọn oniṣẹ ibi naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀