Shiite Movement: Shiite fèsì lórí àṣẹ ilé ẹjọ́ láti máa pé wọ́n ní ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí

Ẹgbẹ Shiite Image copyright @SZakzakyOffice

"Mo lè kú tọmọ tọmọ bi ijọba ba kọ lati da adari wa, ElZakzaky silẹ".

Perete lara ọrọ adari ẹgbẹ ajafẹtọọ musulumi ni iha Guusu-Iwọ Oorun iyẹn ilẹ Yoruba, Comrade Muftau Zakariyah ree nigba ti BBC Yoruba kan si i.

Muftau ni awọn naa gbọ awuyewuye iroyin naa pe ile ẹjọ giga l'Abuja ti paṣẹ pe ẹgbẹ musulumi Shiite ti di agbesumọmi lati igba yii lọ.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ ọ, Ileẹjọ naa tun paṣẹ wi pe ohunkohun tẹgbẹ Shiite ba ṣe bayii ti di ti ẹgbẹ agbesumọmi.

Adari ẹgbẹ yii ni iha Guusu-Iwọ Oorun wa ni bi o ba jẹ aridaju ni pe ijọba Naijiria ṣe eyi, iwa naa ko mọgbọn dani rara.

Idajọ yii waye lẹyin ti ijọba apapọ ni ki ileẹjọ gbe igbesẹ naa lẹyin ti ọga ọlọpaa ati akọroyin Channels ku lasiko iwọde Shiite l'Abuja.

Àgùnbánirọ̀ akọ̀ròyìn Channels náà ti dágbére fáyé látààrí ìkọlù Shiite l'Abuja

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ̀mí sùn níbi ìkọlù Shiite àti ọlọ́pàá

Ẹwẹ, Comrade Muftau ni igbesẹ yii kan da bii ki wọn gbe ote le awọn ẹgbẹ tabi ijọ ẹlẹsin Kristẹni ni tori Naijiria nikan kọ ni ọmọ ẹgbẹ Shiite wa.

"Ṣe aṣoju Iran si Naijiria naa ti di onsunmọmi? Bi ọlọpaa Naijiria tabi ọtẹlẹmuyẹ ba jẹ ọmọ ẹgbẹ Shiite, ṣe ẹ o pe wn ni Sunmọmi".

O ni ijọba to kọkọ ni Sunmọmi ni awọn Fulani ti wọn tun pada ko ọrọ wọn jẹ pe ọmọ Naijiria ni wọn ni wọn wa n pe awọn ti o jẹ ojulowo ọmọ Naijiria bayii ni ẹgbẹ sunmọmi.

"Ṣe ka wa lọ fa ara wa le ọlọpaa lọwọ ni abi ka duro sile ki ọlọpaa wa mu wa?"

Muftau ni ggẹ bi akọsilẹ, laarin ẹgbẹrun mọkanlelogun si ọgbọn ni ọmọ ẹgbẹ Shiite to wa ni Naijiria. " Ṣe wọn wa ni ọgba ẹwọn to le gba gbogbo wa bi wn ba fẹ maa ko wa?".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionN100,000 Nairà mà ni Dino gbé dání lójú agbo, kò náwó yàlà-yòlò - Ayefele

Muftau ni lati igba ti awọn ti maa n ṣe iwọde, ijọba ko figba kan s pe awọn gba eti ẹni kan ri tabi paayan. "Ẹhonu lai lo ibọn tabi ada lawa n ṣe".

Ẹgbẹ wa kii ṣe ẹgbẹ oni jagidijagan, bo ba ṣe pe a fẹ ra ibọ ni, owo wa bẹẹ si ni a ju gbogbo ọmọ ogun Naijiria lọ ṣugbọn kii ṣe ologun tabi ọlọpaa lo ti olori wa mọle bi ko ṣe aarẹ Buhari gangan".

Lati ọdun 2015 lawọn ọmọ ẹgbẹ ti n ṣe iwọde eyi ti wọn fi n beere pe ki ijọba da olori wọn, Sheikh Ibrahim El-Zakzaky, ati iyawo rẹ, Zeenat silẹ.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó

Gbogbo igbiyanju BBC lati kan si awọn ile iṣẹ aarẹ ko fi bẹẹ́ bimọ ire ayafi Bashir Ahmad to jẹ oluranlọwọ pataki fun aarẹ ni ko si ohun to jọ bẹẹ o.

Bashir ni ijọba ko gbe ẹjọ kankan to jọ eyi lọ sile ẹjọ.

Nigba ti akọroyin beere boya wọn ti wa bu omi suuru mu paapaa ti ijọba ko yi igbesẹ pada lori itusilẹ El-Zakzaky.

"Omi suuru bawo... ki lo n jẹ bẹẹ, mi o ni gba, Igba yii gan la ṣẹṣẹ maa jade, bo ba wu wọn ki wọn pa wa".

Mo ṣe tan lati ku tọmọ tọmọ bi wọn ko ba tu ọga wa silẹ tori ẹmi gbogbo awa ọmọ ẹgbẹ ko ni itumọ bi olori wa ba ṣi wa lahamọ".