N100,000 Nairà mà ni Dino gbé dání lójú agbo, kò náwó yàlà-yòlò - Ayefele
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Yinka Ayefele ṣe ìṣirò owó tí Dino ná ní ìsìnkú ìyá rẹ̀

A o kuku ki n fa ori lẹyin olori ni Yoruba wi.

Yinka Ayefele ti eto isinku iya Sẹnetọ Dino Melaye ṣoju rẹ koro gẹgẹ elere to kọrin nibi eto naa dahun si ọrọ to n tan kalẹ pe ṣe ni Dino n nawo bi ọmọ Darosa koda ti ile iṣẹ ọlọpaa ti ni awọn yoo ṣewadi rẹ.

Ṣaaju, Ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn yoo ṣe iwadi fọnran naa to ṣafihan bi Sẹnẹtọ Dino Melaye ti n fi owo mọ olorin Yinka Ayefẹlẹ lori loju agbo.

Igbakeji alukoro fun ile iṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọgbẹni Adeniran Aremu to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ile iṣẹ ọlọpaa yoo gbe igbesẹ to ba yẹ lẹyin to pari iṣẹ iwadi lori fọnran ọhun.

Ẹwẹ niwọn igba to ṣe pe ọkan lara awọn ọlọrọ ninu eyi gan ni Yinka Ayefele funra rẹ, BBC Yoruba kan si i latiṣalaye ọrọ.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii